Ogobotarigi osere ati adẹ́rìn-ín pòsónú , Babatunde Omidina , ti a mọ si baba Suwe ti jẹ Ọlọrun nipe.
Baba Suwe jẹ́pè Ọlọrun lonii yii to jẹ ọjọ kejilelogun osu kọkanla, ọdún, 2021 lẹyin aisan .
Aarẹ ẹgbẹ awọn osere lorilẹ ede Naijiria (TAMPAN) Bolaji Amusan aka Latin lo kede iku osese ọhun..
Itan ranpẹ nipa oloogbe Babatunde Omidina , ti a mọ si baba Suwe
A bi Baba Suwe ọjọ kejilelogun , osu kẹjo ọdun 1958 ni ijọba ibilẹ Ikorodu ni ipinlẹ Eko.
Omidina lo si ile ẹkọ alakọbẹrẹ ti Jamaitul Islamial ni ipinlẹ Eko ati ile ẹkọ ọlọmọ wẹ́wẹ́ to wa ni ilu Osogbo , ki o to lọ si ile ẹkọ girama Adekanbi to wa ni Mile 12, ni ilu Eko.
O jade ile-ẹkọ girama ti Ifeoluwa to wa ni Osogbo ni ipinlẹ Osogbo nibi ti o ti gba iwe-ẹri ile -ẹkọ girama..
Omidina bẹrẹ eré ori sinima lọdun 1971 sugbọn o jẹ ogbontarigi ere sinima , ti okiki rẹ si bẹrẹ si ni kan kaakiri gbogbo agbaye lẹyin igba ti o se eré ti akọle rẹ jẹ , ‘Omolasan’, ni eyi ti Obalende gbe e jade.
Bakan naa, Bab suwe tun di ilu-mọ-ọn-ka ninu eré ti akọle rẹ n jẹ Iru Esin, ni eyi ti Olaiya Igwe gbe jade lọdun 1997. Baba Suwe tun ti ba wọn lọwọ ninu awọn eŕ sinima bii Baba Jaiye Jaiye, ninu eré ti arabinrin Funke Akindele ati Femi Adebayo ti jọ se.
ọmọ ọun mẹtalelọgọrin( 63) ni oloogbe Babatunde Omidina pé , ki o to jade láyé.
Leave a Reply