Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Nàìjíríà yóò ṣàfikún owó ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀

Eyitayọ Oyetunji Fauziat

39

Ìjọba Nàìjíríà sọ pé àwọn ètò ń lọ lọ́wọ́ láti ṣàfikún owó ẹ̀kó alákọ̀ọ́bèrẹ̀ láti ìpín ìdá méjì sí mẹ́ta.

Ijọba naa sọ pe afikun  yii waye latarii imọran ofin ti wọn gbe kalẹ lati mu owo-ifunni pọ si ,lati owo-orii owo-towọle  si eka eto ẹkọ alakọbẹrẹ ti orilẹ-ede.

Minisita fun eto-ẹkọ, Malam Adamu Adamu, fi kun pe, ipin eyọkan ti wọn fikun yi wa fun lati ṣe idoko-wo ni abala ile-ẹkọ giga.

Minisita naa yannana eyi nibi apejọ igbimọ to n ṣamojuto ẹkọ alakọbẹrẹ gbogbogboo (UBE), pẹlu alaga alaṣẹ igbimọ to n ṣamojuto ekọ alakọbẹrẹ gbogbogboo fun ipinlẹ (SUBEBs),eyi ti o waye ni Benin,ni ipinlẹ Ẹdo.

Gẹgẹ bii ẹni ti o ṣoju fun  Oludari  Ẹkọ alakọbẹrẹ, Ile-iṣẹ to n mojuto eto Ẹkọ, Dokita Folake Olatunji-David ṣe sọ, minisita naa sọ pe, iṣakoso ti o wa lọwọlọwọ tun jẹ ipinnu ni kikun lati  ṣatileyin fun  awọn ile-iṣẹ ati lati da awọn tuntun silẹ lati mu ki iṣelọpọ  oṣiṣẹ  pọ si fun awọn oriṣiriṣi abala ọrọ aje orilẹ-ede .

Leave A Reply

Your email address will not be published.