Take a fresh look at your lifestyle.

Àpejọ AFLPM: Àwọn obìnrin àkọ́kọ́ orílẹ̀-èdè adúláwọ̀ gúnlẹ̀ sí Nàìjíríà

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

50

Àwọn ìyáàfin àkọ́kọ́ ilẹ̀ adúláwọ̀ ń gúnlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fún Àpèjọ Gbogbogbòò ẹlẹ́ẹ̀kẹsàn an irú ẹ̀ ti Ìgbìmọ̀ Àlàáfíà àwọn ìyáàfin àkọ́kọ́ (AFLPM,) tí  yóò wáyé ní Ọjọ́ ajé, ọjọ́ kejìlé-lógún, Oṣù kọkànlá ọdún 2021 ní ìlú Àbújá, Olú-ìlú Náìjíríà.

Titi di asiko yii, Iyaafin Aare Naijiria, Aisha Buhari ti gba Iyawo Aare orile-ede Burundi, HE. Iyaafin Angeline Ndayishimiye, Iyaafin akọkọ ti Congo Brazzaville, H.E Antoinette Sassou Nguesso, Iyaafin akọkọ ti Sao Tome H.E Maria de Fatima Vila Nova ati Iyaafin akọkọ ti Sierra Leone, H.E Fatima Maada Bio lalejo.

Iyaafin Buhari tun gba Hon. Oppah Muchinguri Kashiri (Iyaafin), Minisita fun Idaabobo ati Awọn Ogbo Ogun, Zimbabwe, Hon. Iyaafin Toure Nasseneba. Minisita fun Awọn Obirin, Ẹbi ati Awọn ọmọde, Côte d’Ivoire ati H.E, Iyaafin Naha Cheikh Sidiya, Minisita fun  Awujọ, Awọn ọmọde, Mauritania.

A yoo ranti pe wọn da AFLPM silẹ ni ọdun 1997 gẹgẹ bii, agboorun  fun awọn iyawo Awọn olori Ilu Adulawọ ati Ijọba lati ṣe atilẹyin fun adulawọ lapapọ, awọn ẹgbẹ agbegbe, ati awọn ijọba orilẹ-ede lati mu alafia jọba ati idinku laasigbo ati ipa wọn lori ilẹ Adulawọ.

 

 

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.