Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin buwọ́lù ẹ̀yáwọ́ látòkèèrè Fún Àwọn amáyédẹrùn Pàtàkì
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ilé ìgbìmọ̀ asòfin lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti fọwọ́sí ìbéèrè ẹ̀yáwó bílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún dọ́là àti bílíọ̀nù kan Euro lábẹ́ ètò ẹ̀yáwó ìjọba látókèèrè ti ìjọba 2018-2021.
Ifọwọsi naa wa lẹyin ijabọ ile Igbimọ lori iranlọwọ, ẹyawo, gbese ati iṣakoso ti wọn gbekalẹ nibi Apejọ Ile-igbimọ ti Abẹnugan ile, Femi Gbajabiamila ṣe adari rẹ.
Nigbati o n gbe abajade rẹ kalẹ ki wọn to gbaawọle, Alaga Igbimọ, Ahmed Dayyabu Safana sọ pe, ẹyawo naa wa fun lati pese awọn iṣẹ akanṣe ni abala Agbara,ọrọ- Aje ori ayelujara, Ile-iṣẹ, ati abala Ẹkọ.
Awọn toku ni lilọ-bibọ, Iṣowo ati Eto Orilẹ-ede, Ilera, Ọrọ Awọn Obirin, Ayika, ati Ile-iṣẹ Ijọba.
Wọn ṣe agbekalẹ ijabọ lori ibeere eyawo latokeere fun Ile ni ọjọ kẹrinla, Oṣu Kẹwa, ni ọsẹ to koja,ile-igbimọ aṣofin gba wọle ti wọn si buwọlu.
Leave a Reply