Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn ènìyàn mẹ́rìn- lé -lọ́gọ́je míràn tún ti ní ààrun covid

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 409

Àwọn ènìyàn mẹ́rìn-lé-lógójè míràn ló tún ti ní ààrùn covid jákèjádò orílẹ̀-èdè.

Ile-iṣẹ to n mojuto ajakalẹ aarun ni orilẹ-ede, (NCDC), lo fi eleyii taye leti lorii boṣe n lọ.

Ile-iṣẹ ọhun sọ pe, awọn mẹrin-le-logoje ọhun jẹyọ ni ipinlẹ mẹtala lorilẹ-ede.

Ipinlẹ Imo (mejidin-lọgbọn), Plateau-(ogun), Eko- (metadin-logun), Olu-ilu (mẹrindin-logun), Kwara- (mẹẹdogun), Zamfara- (mẹẹdogun ), Ondo- (meje ), Rivers- (marun un ), Taraba- (mẹrin ), Oyo-(mẹta), Bauchi- (meji),  Edo-(ẹyọkan ), Ekiti-(ẹyọkan).

Lọwọlọwọ bayii,eniyan ẹgbẹ́ẹ́ẹdógún- le- ni- ọ̀kẹ́- mẹ̀wá- abọ- o- le- ni- ọ̀kan- le- ni –okòó- lelọ́ọ̀dúnrún lo ti ko aarun naa, ẹgbàáta- le- ni- ọ̀kẹ́- mẹ̀wá- o- le- ni- ẹ̀rin –din- ni- ẹ̀wá-le-nigba eniyan ti gba iwosan,ti ẹ̀ta-din-ni-ojì- din- ni– ẹgbẹ́ẹ́ẹdógún eniyan si ti jẹpe oluwa.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button