Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ti fi ipinnu wọn lelẹ lati daabo bo ẹtọ awon onibaara ọja lorisiirisi laarin Ipinlẹ yii, pẹlu erongba lati fi abadofin tuntun rọpo ofin to wa nilẹ tẹlẹ, lati le ba igba mu.
Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko fọrọ yii mulẹ nibi Ipade awọn alẹnulọrọ ti wọn pe lojuna ati fẹsẹ abadofin tuntun naa mulẹ, eleyii ti wọn pe akọle rẹ ni
“Abadofin kan fun Ofin ti yoo ṣe Agbekalẹ Ajọ ti yoo maa ṣamojuto ẹtọ awọn Onibaara ni Ipinlẹ Eko, ti yoo maa pari aawọ to nii ṣe pẹlu Onibaara ati awon Nnkan miiran to jẹ mọ ọn.”
Ipade Awọn Alẹnulọrọ naa to waye ni gbagede Ile Igbimọ Aṣofin yii ni ilu Ikẹja lọjọ Ẹti Friday ni ọpọ awọn eniyan ti da si abadofin naa, ti wọn n tenu mọ ọn pe wọn gbọdọ jẹ ki ọrọ awọn onibaara jẹ wọn logun ninu ofin naa.
Nigba ti o n ṣagbeyẹwo abadofin naa labala-labala, Olori ọmọ ẹgbẹ oṣelu to pọ julọ ninu Ile Igbimọ Aṣofin naa, Aṣofin Sanai Agunbiade fi mule pe bi won ba so abadofin naa di ofin tan yoo le fun awọn onibaara lagbara lati le beere fun e ẹtọ wọn lọwọ awọn onileeṣẹ. O ni;
“Abadofin yii fun awọn ara ilu lagbara lati ja fun ẹtọ wọn nibi ti wọn ba lero pe awọn onileeṣẹ ti fẹtọ wọn dun wọn. Eyi yoo si jẹ ki ajọ yii le moju to ẹtọ wọn sii. Idi niyi ti ofin naa fun ajọ yii lagbara lati ni ẹka kaakiri agbegbe ijọba ibilẹ ni ipinlẹ yii.”
ọpọ awon eniyan ni wọn gboriyin fun abadofin yii, ti wọn si tun fẹdun ọkan wọn han . Ọkan lara awọn alẹnulọrọ yii, Ọgbeni Wuraola Abdulsalam lati Ẹgbẹ to n ta awọn ohun jijẹ ati awọn ohun eelo pẹẹpẹẹpẹ inu ile, ti o fi itara sọrọ, rọ ile Igbimọ Aṣofin yii lati wọ ọja lo funra wọn lati mọ ohun ti awọn onibaara n koju lọwọ awọn to n ṣe awọn ọja yii. O fẹdun ọkan rẹ han pe ọpọ igba ni awọn maa n ra awọn ayederu ọja tabi eyi to ti pẹ mọ awọn onile-iṣe yii lọwọ, ti a ti da a pada maa di ogun. Eyi si maa n jẹ ofo awọn ni igbẹyin.
Aṣoju Iyalọja Gbogboogbo orile-ede Naijiria, Arabinrin Folaṣade Tinubu-Ojo nibi ipade yii, Arabinrin Abimbọla Jinadu sọ pe ki won ṣagbeyewo abala kejidinlọgbọn abadofin naa, eleyii to nii ṣe pẹlu ṣiṣe abewo si aarin ọja, o ni o yẹ ki ajọ naa maa fi to awọn alakoso ọja leti ki won to wa ṣabẹwo sinu ọja, ko maa ba wọn lojiji.
Alaga Ajọ to n moju to Ẹtọ awọn Onibaara ni Ipinlẹ Eko, iyen LASCOPA, Arabinrin Funmi Falana gboriyin fun Ile Igbimọ Aṣofin yii fun iru abadofin yii. O wa rọ awon onileesẹ ti wọn n pese ohun mimu inu ike lati maa fi asiko ti awọn ohun mimu yii le lo nibi gbigbona ati ibi tutu (temperature) sara awọn ike naa.
Alamojuto Agba Ajọ LASCOPA, Ọgbẹni Afọlabi Ṣolebo gboriyin fun abadofin naa, pe o ti lẹ ti pẹ ti o ti ye ko jade. O salaye pe ajo naa n ri daju pe awon oja ti awon ile-isẹ n se jade ati awọn ti awon ọlọja nla n gbe wọle ni Ipinle Eko, ni awọn n sayẹwo si ko to de ori igba.
Ninu ọrọ Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Eko, Aṣofin Mudashiru Ọbasa, eni ti Igbakeji re, Aṣofin Wasiu Eshinlokun-Sanni ṣoju fun fi mule pe ofin to ba ti yoo de ara ilu lorun ni Ile Igbimọ aṣofin naa maa n se. Eredii eyi ni awọn tun ṣe gbe fe gbe ofin eyi kalẹ lati fi ropọ iru ofin to wa nilẹ tẹlẹ, ki o le ba igba mu. Nigba ti o n fesi si awon ibeere ati ẹhonu awon alenulọrọ nibi ipade naa, o ni gboogbo ibeere wọn ni wọn yoo gbe yẹwo, ki wọn to sọ abadofin naa di ofin. O ni:
“Gẹgẹ bi gbogbo ohun ti wọn sọ, a o si lo jabọ fun Ile. Gbogbo re naa la o si sagbeyẹwo re ni ipele ti igbimọ, ti awọn naa yoo jabọ fun ile ki o to di ofin”
Agbalejo ọjọ naa, ti o tun je alaga Igbimọ to n ri si ọrọ Idokoowo ati Ile-isẹ ninu Ile Igbimọ Aṣofin yii, Aṣofin Bisi Yusuff fi pataki abadofin yii mulẹ bi o ba di ofin tan.
“Abadofin yii yoo le daabo bo ẹtọ awon ara ilu, ti a o si ri idaju pe awọn onibaara mọ ẹtọ won. Ki awọn eniyan mọ ẹtọ rẹ ni. Ko si pe ẹnikan yoo yan ẹnikan jẹ mọ ni asiko yii. A jẹ ki onibaara le gbadun ohun ti o ba fi owo rẹ ra.”
Ọpọ awon ẹlẹgbẹjẹgbẹ ati ile-iṣẹ ni won soju fun nibi ipade alẹnulọrọ naa, bii, Ẹgbẹ awọn Ẹlẹran Iso, Ẹgbẹ awọn Ile-iṣẹ to n pese nnkan, Ẹgbẹ olounje loriṣiirisi, pẹlu awọn ile-iṣẹ ijọba to jẹ mọ eyi.
lagada Abayọmi
Leave a Reply