Take a fresh look at your lifestyle.

Àgbò tó fẹ̀yìn rìn, agbára ló lọ mú wá,Super Eagles fìyà Central Africa Republic jẹ Liberia

123

Ṣé agbo to ba fẹyin rin ni, agbára lo lọ́ mú wa, eyi lo faa ti  Ikọ agbabọọlu  orilẹ ede Naijiria, Super Eagles se  lati gbẹ̀san ìyà ti ikọ̀ agbabọọlu orilẹ-ede Central African Republic fi jẹ wọn ni pápá isere Teslim Balogun ní ile Eko , ti wọn si kanra ìyà naa mọ́  ikọ agbabọọlu  Lone Stars ti orilẹ ede Liberia pẹlu àmì ayò méjì si òdo ( 2-0) tí ikọ agbabọọlu orilẹ ede Liberia ko si lee ta pútú ninu idije ifẹsẹwọnsẹ lati mọ awọn orilẹede wo ni yoo kopa ninu idije ti  ife ẹyẹ bọọlu agbaye lọdun to n bọ.

Idije ọhun waye ni  ilu Tangers lorilẹ ede Morocco.

Victor Osimhen lo gba bọọlu akọkọ wọlu àwọ̀n ikọ agbabọọlu Lone Stars pẹlu pẹnariti nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju karundinlogun ki Ahmed Musa to fọba lee pẹlu pẹnariti miran nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹrinlelaadọrun.

Pẹlu esi ifẹsẹwọnsẹ yii orilẹ ede Naijiria lo wa  loke ipin ‘C’ bayii pẹlu ami mejila ti Cape Verde, Central African Republic ati Liberia si n tẹle pẹlu àmì mẹwaa, mẹrin ati mẹta ni ṣisẹ -n -tẹle.

Leave A Reply

Your email address will not be published.