Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Bùhárí kí Gómìnà Anambra tí wọ́n dìbò yàn kú oríire

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 281

Ààre Mùhámmádù Bùhárí ti kí ọ̀jọ̀gbọ́n Charles Chukwuma Soludo, olùdíje fún ẹgbẹ́ All Progressives Grand Alliance (APGA) kú oríire  bí ó ti jáwé olúborí nínú ìdìbò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Anambra.

Aare naa gboriyìn fun awọn ile-iṣẹ aabo, fun ipinnu wọn lati rii daju pe idibo naa lọ ni irọrun , ati Igbimọ idibo ti orile-ede olominira (INEC) naa fun ṣiṣe idije naa ni aṣeyọri, laibikita awọn italaya ti o kọkọ waye.

Ààrẹ Buhari ní kí Ọ̀jọ̀gbọ́n Soludo tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀  ìgbimọ̀ràn ọrọ̀ ajé ààrẹ,  kó àwọn ti wọn jọ n ṣiṣe papọ jọ láti kojú àwọn ìpèníjà kanka tí ń dojú kọ Ìpínlẹ̀ àti Gúúsù Ìlà Oòrùn lápapọ̀.

Ninu ifiranṣẹ aarẹ kan,o sọ pe ohun nireti lati ṣiṣẹ pẹlu Gomina ti o  wọle ni alaafia, aabo to peye ati idagbasoke, ti kii ṣe fun  Ipinlẹ Anambra nikan, ṣugbọn ti  gbogbo orilẹ-ede.

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button