Anambra Decides: Ọ̀jọ̀gbọ́n Sólúdò jáwé olúborí ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́tà-dínlógún lábé àsìá APGA
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Grand Alliance, APGA, ti jáwé olúborí ní àwọn ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́tàdínlógún [17] nínú àwọn ìpínlẹ̀ mọ́kàn-dínlógún [19] gẹ́gẹ́ bíí àjọ elétò ìdìbò orílè-èdè (INEC) ṣe kéde nínú ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra.
Ninu esi iwọ oorun Anambra, eyi ti osise ajo INEC to n pada sipo, Dokita German Anagbogu kede, APC ni èje-din-ni-ojì le ni ẹgbẹ́fà,PDP ni ọ̀kan le ni ẹgbẹ́je nigba ti APGA ti o jawe olubori si ni èjì din ni okòó-le-ni-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́wá.
Lọwọlọwọ bayii, wọn ti fagile ibo ti wọn si tun ti sun idibo ni Ihiala siwaju, si ọjọ kẹtala, oṣu kọkanla.
Igbimọ idibo tun kede pe ko si idibo ti o waye ni ijọba ibilẹ kan ati ọkan ti o ni ẹru pẹlu awọn ọran ti ko tii yanju.
Awọn ijọba agbegbe ti o kan ni Ihiala ati Orumba ni ariwa lẹsẹẹsẹ.
Leave a Reply