Ààrẹ orìlẹ̀ èdè Nàíjíríà Muhammadu Buhari ti ṣe ifilọlẹ E-Naira, owo ẹrọ ayelujara.
Ayẹyẹ naa waye lọjọ Aje ni ile aarẹ to wa niluu Abuja.
Aarẹ sọrọ yii lasiko ti alakoso ile-ifowopamọ ti orilẹ ede Naijiria,(Central Bank of Nigeria ,CBN) se ifilọlẹ owo ori ẹrọ ayelujara E-Naira ni ile aarẹ to wa niluu Abuja.
Aarẹ tun sọ pe irinajo owo E-naira bẹrẹ lati bi ọdun mẹta sẹyin . Aarẹ ni ile-isẹ ijọba ati ile-ifowopamọ ti orilẹ ede Naijria lo fọwọsowọpọ lati gbe eto yii jade.
Aarẹ wa gbosuba fun alakoso ile-ifowopamọ ti orilẹ ede Naijiria,(Central Bank of Nigeria ,CBN) fun gudu gudu meje, yaya mẹfa ti o se fun ifilọlẹ e-Naira yii.
Alakoso ile-ifowopamọ ti orilẹ ede Naijiria,(Central Bank of Nigeria ,CBN)Emefiele naa tun sọ pe owo ori ẹrọ ayelujara yii yoo jẹ ki itẹsiwaju ba eto ọrọ aje orilẹ ede Naijiria ati gbogbo awọn ọmọ orilẹ ede Naijria lapapọ.
Leave a Reply