Ẹgbẹ́ awọn osisẹ lorilẹ ede Naijiria ti kilọ fun ijọba apapọ lati maa fi tipa fun awọn osisẹ ni abẹrẹ ajẹsara COVID-19 .
Aarẹẹgbẹ awọn osisẹ lorilẹ ede Naijiria ,ọgbẹni Ayuba Wabba lo sekilọ yii lasiko to n ba awọn osisẹ ijọba apapọ sọrọ nipa abẹrẹ ajẹsara COVID-19, niluu Abuja.
O sọ pe ijọba apapọ gbọdọ rọ awọn osisẹ lati gba abẹrẹ ajẹsara COVID-19 kii ṣe nipa lilo kàńpá tabi ipá.
Araẹ egbẹ awọn osisẹ wa rọ ijọba apapọ lati seto bi awọn osisẹ yoo se ri awọn abẹrẹ ajẹsara COVID-19 yii gba nile isẹ wọn.
Ti a o ba gbagbe pe ni ọọ kẹtala ,osu kẹwaa, ọun 2021 ni akọwe agba fun ijọba apapọ ti o tun jẹ ọkan lara igbimọ ijọba to n samojuto gbigbogun ti arun COVID-19 sọ pe ẹnikẹni ninu osisẹ ijọba ti ko ba ni ẹ̀rí pe oun ti gba abẹrẹ ajẹsara COVID -19 laarin ọjọ mẹta , wọn o ni jẹko wọ ile-isẹ rẹ, bẹrẹ ni ọjọ kin-in-ni osu kejila, ọdun 2021.
Leave a Reply