Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ dẹ́kun nípa bíba àwọn ọ̀pá epo jẹ́ – à̀arẹ Buhari

0 302

Aarẹ orilẹ ede Naijiria,Muhammadu Buhari ti rọ awọn oludari Ogoni  to wa ni ẹkùn  Niger-Delta lati  tubọ maa rọ awọn eniyan lati maa daabobo awọn ohun ìnì  bii ọ̀pá epo rọbi  ati awọn ti wọn lo lati pọn epo rọbi ni orilẹ ede yii.

Aarẹ Buhari tun wa rọ wọn lati dẹkun nipa bíba awọn ohun elo epo rọbi jẹ́ , nitori eyi  lee fa  idena eto idagbasoke ní ẹkun naa.

Aarẹ sọrọ yii lasiko to n tẹwọgba awọn oludari  ilu Ogoni  ni ẹkun  Niger-Delta lọjọ Ẹti nile aarẹ to wa niluu Abuja.

Aarẹ Buhari  ni ijọba ti setan lati se atunse si ilu Ogoni ati lati mu tẹsiwaju ninu eto idagbasoke ilu naa., ki awọn eniyan ilu naa lee padi si isẹ agbẹ wọn.

 

 

Ninu ọrọ rẹ, aarẹ igbimọ awọn lọba-lọba ti  Ogoni , ọba Godwin Giniwa, wa dupẹ lọwọ aarẹ Buhari fun eto idagbasoke ti ijọba rẹ dawọle ni awọn ayika ti epo rọbi ti bàjẹ́.

Awọn ọba  naa tun tẹsiwaju pe awọn fẹ́ ki isọkan orilẹ ede Naijiria tun tẹsiwaju nitori pe , nipa eyi ni ọjọ́ iwaju rere awọn eniyan  se waa si ìmúsẹ.

O tun wa gbosuba fun aarẹ Buhari nipa awọn ohun amayedẹrun bi ipese irinna ọkọ oju-irin ati eto idagbsoke oju popo ti ijọba rẹ gunle lati mu idẹrun ba gbogbo ọmọ orilẹ ede Naijiria, o tun wa rọ aarẹ Buhari  lati pese omi ẹrọ igbalode fun  ẹkun wọn..

 

 

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button