Oludari ile akede Naijiria,( Voice of Nigeria, VON), Osita Okechukwu ti sapejuwe ile -itọju arun jẹjẹrẹ ti wọn kọ si ipinlẹ Kano gẹgẹ bi eto iranwọ fun awọn to ba ni arun ọhun..
O tẹsiwaju pe ierti ti wa bayii fun itọju arun gbẹ̀mí-gbẹ̀mí jẹjẹrẹ lẹyin itọju arun ọhun ni ile-iwosan naa.
Osita se alaye yii lasiko irinajo ti gomina ipinlẹ Kano seto fun ẹgbe awọn oludari ile isẹ redio ati mohun-maworan lorilẹ ede Naijiria ,lasiko ipade apero ọlọdọọdun ti wọn maa n se, ni eyi to waye ni ipinlẹ Kano.
o tun sọ pe saaju asiko yii ni arun jẹjẹrẹ ti maa n gbẹmi ọmọde ati agbalagba , ti o si jẹ pe arun yii ti sọ abiku di oloogun èké nitori pe ko see tọju.Amọsa pẹlu ile-iwosan fun itọje arun jẹjẹrẹ ti ijọba ipinlẹ Kano kọ yii, o daju pe ireti ti wa fun awọn to ba ni arun jẹjẹrẹ lorilẹ ede Naijiria.
Osita wa gbosuba fun ijọba ipinlẹ Kano fun gudu gudu meje yaya mẹfa ti wọn se
Leave a Reply