Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ jẹ́ kí ìsọ̀kan Nàíjíríà jẹ wá lógún, tí Nàíjíríà bá pín, gbogbo wa la ó pàdánù

0 246

Igbakeji aarẹ orilẹ ede Naijiria, ọjọgbọn Yemi Osinbajo ti gbosuba fun awọn akọroyin orilẹ ede Naijiria fun gudu-gudu meje , yaya mẹfa ti wọn n se lati lee jẹ” alabojuto eto aabo fun awọn ara ilu“.

Ọjọgbọn  Osinbajo sọrọ yii lasiko ti  o gba ẹgbẹ awọn akọroyin ( Nigerian Union of Journalists ,NUJ), ti aarẹ ẹgbẹ naa , Chris Isiguzo dari rẹ , lalejo  lọjọ Aje ,nile aarẹ to wa niluu Abuja.

Igbakeji aarẹ wá rán awọn akọroyin leti pe   “Gbogbo  wa, ni a ni orilẹ ede Naijiria , yala , o jẹ́ akọroyin, oloselu tabi ẹlẹsin kan tabi ekeji  , orilẹ ede Naijiria, jẹ ti gbogbo wa , a si gbọdọ sa ipa wa lati ri i pe orilẹ ede Naijiria wa ni alaafia , ki o si jẹ ọ̀kan.” 

Aarẹ ẹgbẹ awọn akọroyin lorilẹ ede Naijiria, Chris Isiguzo naa wa gbosuba fun gudu-gudu meje ,yaya mẹfa ti ijọba aarẹ  Buhari n ṣe , paapaa julọ nipa pipese isẹ lọpọ janturu fun awọn ọdọ lorilẹ ede Naijiria.

 

Isiguzo   tun tẹsiwaju pe ẹgbẹ awọn akọroyin koro ojú si awọn iroyin ẹlẹ́jẹ̀ ti awọn kan maa n gbe jade , nitori naa ,ijọba rẹ yoo sa gbogbo ipa lati ri i pe wọn gbogun ti  irú iwa ibajẹ bẹẹ.

Owó ìrànwọ́
TAarẹ ẹgbẹ awọn akọroyin  wa rọ ijọba lati ran awọn ile-isẹ akọroyin lọwọ nipa fifun wọn ni owo iranwọ , o ni pupọ ninu ile-isẹ iroyin  lo n koju ipenija bayii, ti eyi si ti jẹ ki wọn da osisẹ wọn silẹ, ti awọn miran si tun  ti din iye owó ti wọn n san fun awọn osisẹ wọn kù.

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button