Igbimọ awọn gomina to wa ni aarin gbungbun orilẹ ede Naijiria yoo se ipade laipẹ lati jiroro nipa ipenija to n dojukọ ipinlẹ wọn lori eto aabo
Gẹgẹ bi alaga igbimọ ọhun, ti o tun jẹ gomina ipinlẹ Plateau, Simon Lalong, se sọ pe ipade naa ni wọn yoo ti maa jiroro lori ipenija to n dojukọ ẹkun wọn paapaa julọ nipa iwa ijinigbe, ọdaran ati bẹẹbẹẹ lọ.
Saaju eyi ni gomina ipinlẹ Kaduna, Nasiru El-Rufai , ti se ipade pajawiri pẹlu nipa ipenija to n dojukọ eto aabo ni ẹkun wọn.
Ninu ọrọ rẹ, alaga awọn ọba ni ẹkun Ariwa , Sultan ti ipinlẹ Sokoto, Sa’ad Abubakar ti bi ọpọ awọn eniyan se wa si ipade yi idaniloju pe gbogbo awọn gomina ti setan lti gbogun ti ipenija ati isoro to n dojukọ ẹkun wọn.
Leave a Reply