Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ máa fojú yẹpẹre wo àsà Yorùbá, ẹ gbé èdè, àṣà, lítíréṣọ́ Yorùbá lárugẹ-Ọọ̀ni Ifẹ̀

Ademọla Adepọju

0 492

Ọọniriṣa Alayeluwa, Ọba Adeyẹye Ogunwusi Ọjaja Keji, Ọọni Ifẹ  ti pe fun gbigbe aṣa ati ede Yoruba larugẹ nipa lilo  oriṣiiriṣi ọna .

Ọọniriṣa, ẹni ti ỌbaAdebisi Layade (JP), Alara Oodaye ti Ilu Ara ni Ile-Ifẹ ni Ipinlẹ Ọṣun ṣoju fun ni o sọrọ yii di mimọ nibi ayẹyẹ ifilọlẹ iwe kan ti wọn kọ nipa igbesi aye oloogbe  Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ, eyi ti wọn fi n ṣe iranti ọdun kẹfa ti Oloogbe Oloye Hannah Idowu Dideolu Awolọwọ jade laye, eyi ti wọn pe akọle rẹ ni, ‘Awolọwọ Akikanju Aṣiwaju (AAA)’ lati ọwọ Lagada-Abayọmi Ọlanrewaju.

Kabiyesi rọ awọn lọbạ-lọba ati loye-loye ilu lati maa ṣagbatẹru gbigbe ede Yoruba larugẹ gẹgẹ bi ọna ti aṣa Yoruba ko fi ni parun. Wọn ni:

“Ọpọ awọn eniyan bayii, bi wọn ba kuro ni ilu tabi orilẹ-ede wọn, wọn a gbe sisọ ede Gẹẹsi bori ede Yoruba. O ti di aṣa temi bi n ba lọ soke ọya lọhun un, emi ki i sọ ede miiran ju Yoruba lọ. Bi wọn ba si fura si eyi, maa sọ pe ki wọn lọ gba ongbufọ fun mi.”

Mo si mọọmọ ṣe eyi ni lati fi maa gbe ede wa larugẹ, nitori ọpọ awọn ibomiran ni wọn n lo ede abinibi wọn lati fi kọ awọn ọmọ lẹkọọ. Yoruba dun-un tu si ede miiran, o si dara lati fi kọ ọmọde lẹkọọ.”

 

Ninu ọrọ Alaga ayẹyẹ ifilọwẹ iwe ati fọnran naa, Ọba Ọldipọ Ọlaitan, Alaago ti Kajọla Alaago ni Ipinlẹ Ọṣun ti wọn jẹ Igbakeji Olori Ẹgbẹ Ajafẹtọọ ọmọ Yoruba, iyẹn Afẹnifẹre, wọn ni gbogbo ipa la gbọdọ sa lati daabo bo ede Yoruba ti ko fi ni parun. Wọn ni:

“Inu mi dun pupọ si ayẹyẹ yii ti a fi n gbe ede Yoruba larugẹ. Nigba ti ọmọ Yorubako ba le sọ ede abinibi rẹ, eleyii ko bojumu rara. O rira rẹ gẹgẹ bi ẹni ti o ti ṣaṣeyọri nitori pe o le sọ ede Gẹẹsi, Faranse, ‘German’ ṣugbọn ko le so ede abinibi tirẹ. Ọmọ orilẹ-ede Germany a sọ ede tirẹ nibikbi to ba de, paapaa julọ, ninu Ajọ Iṣokan orilẹ-ede agbaye, UN, bakan naa lọmọ orilẹ-ede Faranse a sọ tirẹ, amọ bi awa ba de ọhun, ede Gẹẹsi laa maa sọ, eyi ko boju mu rara.”

Bakan naa, ni Kabiyesi tun gboriyin fun awọn iṣẹ akin ti Oloye Awolọwọ ṣe nigba aye rẹ, eleyii ti o n fi ẹdun ọkan han si bi nnkan ṣe wa yi pada bayii si isẹ rere ti Awolọwọ fi lelẹ fun ijọba rere.

Aṣofin Setonji David to jẹ Alaga Igbimọ to n mojuto Iroyin, Ọgbọn Iṣelu ati eto Aabo ninu Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, ẹni ti o ṣoju fun Oludari Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko, Aṣofin Mudashiru Ajayi Ọbasa naa sọ pe o ṣe pataki lati daabo ede Yoruba. O ni:

“Gbogbo ohun to ba nii ṣe pẹlu ede maa n jẹ emi logun, niwọn to jẹ pe ọkan wa maa n balẹ bi a ba sọ ede abinibi wa. Orilẹ-ede korilẹ-ede ti o ba fẹ gun oke agba gbọdọ pada si ede abinibi rẹ. O rọrun fun awọn orilẹ-ede ni ilẹ Asia lati ni idagbasoke nitori wọn n fi ede wọn ṣe nnkan gbogbo. A ni lati gbe ede Yoruba larugẹ”

Bakan naa ni Aṣofin naa tun gboriyin fun iṣẹ akin oloogbe Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ nigba aye rẹ. O woye pe oun gan-an funra oun jẹ anfaani eto ẹkọ ọfẹ ijoba rẹ nigba naa ni Ipinlẹ Eko.

Onkowe iwe naa, ‘Awolọwọ Akikanju Aṣiwaju (AAA)’, Ọgbẹni Lagada-Abayọmi Ọlanrewaju, ti o tun jẹ olori ẹka ede Yoruba Ile Akede Naijiria (Voice of Nigeria), nigba ti o n ba awọn oniroyin sọrọ, o ṣalaye pe ohun ti o ṣokunfa kikọ iwe naa ni pe ọpọ awọn iwe alarogun bayii ni ilẹ okeere ni wọn fi n gbe awọn akin wọn larugẹ, paapaa  julọ, awọn akin ti a foju ri, ṣugbọn ti iru rẹ ṣọwọn lede Yoruba.

O ṣalaye pe iru igbesẹ yii yoo le jẹ ki awọn ọdọ iwoyi le kọ ọgbọn kan tabi omiran ninu iṣẹ akin bayii. O ni:

“Bi ko ṣe fi bẹẹ si awọn iṣẹ atinuda bayii to n sọ nipa iṣẹ akin awọn akọni wa, paapaa julọ, awọn ti a ba laye, ti awọn ọmọde iwoyi yoo le ti ara wọn kọ ọgbọn, eleyii lo ṣokunfa a ti mo fi kọ iwe yii lori akọni wa kan, Oloogbe Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ.”

 

Lara awọn to tun wa nibi ayẹyẹ ifilọlẹ iwe yii ni Onimọ-ẹrọ Olufẹmi Alao, oludasilẹ ile-iṣẹ imọ-ẹrọ FBC, ti wọn jẹ olufilọlẹ agba nibi ayẹyẹ naa, awọn aṣoju lati ile-iṣẹ ijọba gbogbo ati awọn ile-iṣẹ miiran.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button