Take a fresh look at your lifestyle.

Ìkọlù NDA : Alákóso ṣàgbékalẹ̀ ìjábọ̀ fún ilé Ìgbìmọ̀

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 186

Alákóso Ilé -ẹ̀kọ́ gíga ti Ìdàábòbò Nàìjíríà, NDA, ti tún tẹnumọ pé  ìgbìyànjú ń lọ lọ́wọ́ láti gba ọmọ -ogun tí wọ́n jí gbé ní ilé -iṣẹ́ náà ní Oṣù Kẹjọ àti láti  ríi dájú pé irúu ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ mọ́.

Major General Ibrahim Yusuf sọ eyi di mimọ lakoko ti o n ṣafihan ijabọ  lori ikọlu awọn ọlọsa ti o waye ni NDA,ni  Ọjọ kẹrinle-logun,oṣu kẹjọ,  fun awọn ọmọ ẹgbẹ  Igbimọ Ile  Aṣoju lori Aabo.

O  ṣe apejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi ohun ti o bani ninujẹ pupọ, Major General Yusuf, sọ pe gbogbo awọn agba ajagun ti ṣabẹwo si ile -ẹkọ giga naa lati ṣe ibajọpọ pẹlu agbegbe ile -ẹkọ ati lati ṣe ifọrọwani lẹnu wo diẹ sii lori ohun ti ile -ẹkọ giga n ṣe lati rii daju pe iṣẹlẹ naa ko waye mọ.

Nibayi, Minisita fun Aabo,  ajagunfẹyìntì Major General Bashir Magashi, tun ti ṣe alaye fun awọn aṣofin lori adehun laarin Ijọba Naijiria ati ijọba apapọ orilẹ-ede Russia  lori igbejako onijagidijagan, iṣọtẹ, jijini gbe ati gbogbo awọn iwa buburu miiran ati awọn ipa wọn lori aabo orilẹ -ede.

 

Alaga  Igbimọ naa, Ọgbẹni Babajimi Benson, ninu asọye iṣaaju ki wọn to ṣe  ipade bo nkẹlẹ meji naa pẹlu awọn ọmọ igbimọ aṣofin lori aabo, sọ pe awọn ijabọ wọnyii yoo tunbọ tan imọlẹ  sii  iṣẹlẹ naa ati awọn igbese ti wọn gbe kalẹ lati maa jẹ  ki iṣẹlẹ miiran ṣẹlẹ mọ,  ti o si  tan imọlẹ si adehun ti o wa  laarin Naijiria ati Russia.

 

 

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.