Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ MÁA FÀYÈ GBA ÀWỌN ONÍJIBÌTÌ AYÉLUJÁRA NÍLÉ-ÌGBAFẸ́ YIN-EFCC

Abiola Olowe lati Ibadan

101

Ile- isẹ to n dena iwa ibajẹ ati sise owo ilu kumọkumọ lorilẹ ede Naijiria, EFCC ti se ikilọ fun awọn onile igbafẹ jake -jado orilẹ ede Naijiria lati dẹkun fifi aye gba awọn to n lu jibiti ori ẹrọ ayelujara layika wọn.

Ajo EFCC lo se ikilọ yii lasiko ti awọn osisẹ ẹkun ajọ naa to wa ni ilu Ibadan ti i se olu- ilu ipinlẹ Ọyọ, ni ẹkun gusu iwọ oorun orilẹ ede Naijiria n se isẹ́ iriju wọn, ninu eyi ti ajọ ọhun ri awọn afurasi onijibiti ori ẹrọ ayelujara mẹrindinlọgọta mu ni ilu Abẹokuta ti i se olu ilu ipinlẹ Ogun.

Awọn afurasi ọhun ni awọn ajọ EFCC ko ni ile igbafe kan, eleyi ti wọn fi farapamọ si ni ilu Abẹokuta lẹyin ifimufinlẹ ati iwadii ti wẹn ti bẹrẹ lati ọsẹ diẹ sẹyin, ninu eyi ti ajo EFCC koro oju si lilẹ-idi apo mọ awọn afurasi ọhun, ni eyi ti o ran wọn lọwọ lati na papa bora. Igbesẹ ti awon onile igbafẹ naa gbe ni o lodi si abala ikeji iwe ofin (38) EFCC, ọdun 2004.

Latari eyi ni ajọ EFCC se jẹ ki o di mimẹ fun gbogbo onile igbafẹ pe, oju ewe kẹta iwe ofin “Advance Fee Fraud and Other Related Offences” ọdun 2006 ti fidi rẹ mulẹ pe èwọ̀n ọdun marun un si mẹẹdogun lo wa fun eni yoowu to ba fi aaye silẹ fun enikeni lati lu jibiti ori ẹrọ ayelujara ni ile tabi ayika ile rẹ, laisi anfaani sisan owo itanran.

Ajọ EFCC wa salaye siwaju  pe, ti awọn onile igbafẹ ko ba se agbodegba fun awọn onijibiti ori ẹ̀rọ ayelujara, gẹgẹ bi ẹsun ti wọn fi kan wọn, wọn ni lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro lati se isẹ wọn .

Lara awọn ohun ti ajọ EFCC ri gba ni ọkọ ayọkẹlẹ bi i mẹwa; oniruru ẹrọ ilewọ ibaraẹnisọrọ; ẹrọ agbele’tan ti a mọ si laptop ati awọn nnkan miran to tọkasi isẹ jibiti ti wọn n se.

Leave A Reply

Your email address will not be published.