Take a fresh look at your lifestyle.

A ó fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àjọ EFCC láti gbógun ti ìwà jìbìtì orí ẹ̀rọ ayélujára- ilé isẹ́ agbófinró

77

Kọmisọna fun ile isẹ ọlọpaa ni ipinlẹ  Kwara , Amienbo Tuesday Assayomo  ti seleri pe ile isẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara yoo fọwọsowọpọ pẹlu ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati sise owó ilu kumọ-kumọ lorilẹ ede Naijiria, EFCC  lati gbogun ti awọn oniwa jibiti ori ẹrọ ayelujara ni ipinlẹ naa.

o sọrọ yii lasiko ti o kọwọrin pẹlu ikọ rẹ lọ si ẹkun ajọ EFCC  to wa ni ilu Ilọrin.Kọmisọna tẹsiwaju  lati fi ẹhonu rẹ han nipa bi awọn ọdọ to yẹ ko wulo fun orilẹ ede  Naijiria, se n lọwọ ninu iwa ibajẹ  ori ẹrọ ayelujara. O ni ifọwọsowọpọ  gbogbo awọn agbofinro nikan lo lee wa gbogbo iwa ibajẹ to n waye lorilẹ ede Naijiria bolẹ̀.

Kọmisọna tun wa lo asiko ọhun lati pe adari ajọ EFCC ti ẹkun ọhun lati wa pade adari ile-isẹ ọlọpaa to orilẹ ede Naijiria ,, Usman Alkali Baba, ti o n bọ ni ipinlẹ Kwara . lati wa bẹ ipinlẹ naa wo.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.