Waziri-Azi di adarí àjọ tó ń gbógun ti fífi ènìyàn ṣe òwò ẹrú NAPTIP
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ààrẹ Mùhámmádù Bùhárí ti fọwọ́ sí yíyan Dọ́kítà Fatima Waziri- Azi, gẹ́gẹ́ bí Olùdarí Gbogbogbò fún àjọ tó ń gbógun ti fífi ènìyàn ṣe òwò ẹrú (NAPTIP) .
Eyi jẹ atẹle si iṣeduro Minisita fun ọrọ ọmọniyan, Isakoso Ajalu ati Idagbasoke Awujọ, Sadiya Umar Farouq, ti o ṣalaye pe “iwulo riro Ile -iṣẹ NAPTIP lagbara kun agbara ti o ni tẹlẹ lati l’abajade aṣeyọri ni agbegbe ti a fẹ ṣe pataki pupọ.”
O ṣafikun pe, iṣeduro fun Fatima Waziri-Azi da lori “ijọmọ luabi, iriri to gbooro ati awọn iṣẹ takun takun ti yoo mu ile-iṣẹ ọhun nilọsiwaju ti yoo si tun ṣafikun awọn aṣeyọri ti o ti n ṣe bọ tẹlẹ.”
O jẹ ọga agba tẹlẹ fun Ẹka Ofin ti Gbogbogbo ni Ile-ẹkọ giga ti Naijiria ti Ijinlẹ Ofin , Waziri-Azi jẹ olugbeja fun Awọn Obirin, olupolongo igbogun ti iwa-ipa abẹ- ile ati ibalopọ pẹlu ipa ti o si tun jẹ amofin .
Leave a Reply