Take a fresh look at your lifestyle.

Waziri-Azi di adarí àjọ tó ń gbógun ti fífi ènìyàn ṣe òwò ẹrú NAPTIP

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

141

Ààrẹ Mùhámmádù Bùhárí ti fọwọ́ sí yíyan Dọ́kítà Fatima Waziri- Azi,  gẹ́gẹ́ bí Olùdarí Gbogbogbò fún àjọ tó ń gbógun ti fífi ènìyàn ṣe òwò ẹrú (NAPTIP) .

Eyi jẹ atẹle si iṣeduro  Minisita fun ọrọ ọmọniyan, Isakoso Ajalu ati Idagbasoke Awujọ, Sadiya Umar Farouq, ti o ṣalaye pe “iwulo riro  Ile -iṣẹ NAPTIP lagbara  kun agbara ti o ni tẹlẹ  lati l’abajade aṣeyọri ni agbegbe ti a  fẹ ṣe pataki pupọ.”

O ṣafikun pe, iṣeduro fun Fatima Waziri-Azi da lori “ijọmọ luabi, iriri to gbooro ati awọn iṣẹ takun takun  ti yoo mu ile-iṣẹ ọhun  nilọsiwaju ti  yoo si tun ṣafikun awọn  aṣeyọri ti o ti n ṣe bọ tẹlẹ.”

O jẹ ọga agba tẹlẹ fun Ẹka Ofin ti Gbogbogbo ni Ile-ẹkọ giga ti Naijiria ti Ijinlẹ Ofin , Waziri-Azi jẹ olugbeja  fun Awọn Obirin, olupolongo igbogun ti   iwa-ipa abẹ- ile ati ibalopọ pẹlu ipa ti o si tun jẹ amofin .

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.