Take a fresh look at your lifestyle.

Nàìjíríà, Saudi Arabia fọwọ́sowọ́pọ̀ láti gbógun ti ìpaniláyà àgbáyé

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

102

Nàíjíríà àti Saudi Arabia ti ṣe àdéhùn mofaramọ́ àti ìfọwósowópò láti gbógun ti  ìpániláyà àgbáyé.

Awọn orilẹ -ede mejeeji ṣe adehun naa nigbati Minisita Naijiria fun eto ọrọ okeere, Ọgbẹni Geoffrey Onyeama, gba  Minisita eto ọrọ okeere fun orilẹ-ede Saudi Arabia, Faisal bin Far han Al Saud,l’alejo ninu ọfiisi rẹ, ni Abuja, Naijiria.

Ọgbẹni Onyeama sọ ​​pe, Saudi Arabia ati Naijiria ti jọ ni ajọṣepọ to danmọran ni aimọye ọdun sẹyin, o tun wa tẹnumọ  ipinnu  awọn orilẹ -ede mejeeji lati dojuko ipanilaya, paapaa ni agbegbe Sahel ati awọn apakan miiran ti agbaye.

Lori ibaṣepọ iṣowo laarin awọn orilẹ -ede mejeeji, Minisita fun ọrọ okeere orilẹ-ede Naijiria, fihan kedere pe Naijiria ati Saudi Arabia ti tunbọ tẹra mọ ajọṣepọ eto -ọrọ aje wọn lati ṣe alekun iwọn iṣowo ti o wa laarin awọn orilẹ -ede mejeeji.

Ọgbẹni Onyeama sọ ​​pe, Igbimọ Apapọ  Naijiria ati Saudi Arabia ti gbaradi  lati ṣe alekun iṣowo laarin awọn orilẹ -ede mejeeji.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.