Take a fresh look at your lifestyle.

A mú ètò ààbò lọ́kúnkúndùn ju ètò ọrọ̀ ajé lọ- Mínísítà ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

112

Mínísítà fún ètò Ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti ọ̀rọ̀ ajé orí ayélujára, Ọ̀jọ̀gbọ́n Isa Pantamí, sọ pé ẹ̀ka ìbáraẹnisọ̀rọ̀  mú  ààbò lọ́kúnkúndùn ju àwọn àǹfàní ètò -ọrọ̀ ajé lọ.

O sọ eyi  ni ilu Abuja, lakoko ayẹyẹ ifilọlẹ ilana eto Ibanisọrọ ti Igbimọ Ibaraẹnisọrọ Naijiria (SVP), 2021-2025, iwe akojọ awọn ọrọ ati awọn agbejade  Ọjọgbọn Umar Danbatta  ti akole rẹ jẹ “Catalyzing Nigeria Socio-Economic Transformation through Broadband Infrastructure” ati Podcast NCC.

Ọjọgbọn Isa Pantami salaye pe, Ile -iṣẹ ati Igbimọ ọhun ko ṣe awada pẹlu aabo ati pe, nitori ohun ti wọn fi n ṣe iranlọwọ fun awọn ile-iṣẹ aabo , wọn padanu awọn anfani eto -ọrọ aje ti ko ba  wa si eka naa.

“A  ti n padanu  lori ilosiwaju ọrọ -aje ti eka wa  nitori akitiyan wa lati  ṣatilẹyin fun  ile-iṣẹ aabo. Ni  eyikeyi  akoko ni eka ibaraẹnisọrọ, ipo  aabo ṣaaju  awọn anfani eto -ọrọ aje. Aabo kọkọ jẹ wa logun ti  awọn anfani eto -ọrọ aje si tẹle. Ṣugbọn ti a ba le lepa ohun meji ;eleyi  jẹ pataki akọkọ.

Sibẹsibẹ o fidi rẹ mulẹ pe,wọn ti ṣe ọpọlọpọ  akitiyan lori  ilọsiwaju aabo  orilẹ -ede.

 

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.