Take a fresh look at your lifestyle.

Ìyanṣẹ́lódì àwọn dókítà: A ti Ṣe àṣeyọrí tó nítumọ̀ -–Mínísítà ètò Iṣẹ́

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

213

Ìjọba orílẹ̀ -èdè Nàìjíríà sọ pé òhun ti yanjú gbogbo àwọn nǹkan  tí àwọn dókítà Oníségùn ń bèèrè fún, àyàfi èyí tí ó lòdì sófin “kò sí iṣẹ́  kò sáwó”.

Nitorinaa, ijọba n kepe awọn ọmọ ẹgbẹ dokita lapapọ lati fopin si iyanṣẹlodi ti wọn bẹrẹ lati bii ọjọ mẹtale-lọgbọn.

Minisita fun eto Iṣẹ ati ironilagbara, Dokita Chris Ngige ṣalaye eyi fun awọn oniroyin Ile -ilu lẹhin ti o ṣe ipade bonkẹlẹ pẹlu aarẹ Muhammadu Buhari.

O sọ pe ijọba orilẹ -ede Naijiria ko ni lọwọ ninu iru adehun bẹẹ tabi  iru ibeere bẹ.

Minisita naa sọ pe, o ṣeni laanu pe, idaṣẹsilẹ ọhun ti  n pẹ, nigba miiran, awọn eniyan to n ṣe  awọn iṣẹ pataki bi eka ilera ko kii kan daṣẹsilẹ lainidii.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.