Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn ológun fipá gbàjọba ní orílẹ̀-èdè Guinea

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

111

Ìjọba orílẹ -èdè Nàìjíríà  bẹnu àtẹ́ lu ìfipá gbàbjọba tó wáyé ní orílẹ̀-èdè Guinea Ní ọjọ́ kẹfà, Oṣù Kẹsàn án, ọdún 2021, ó ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi “ó jẹ́ ìfọwọ́ pòfin  Ìlànà àjọ tó ń mójútó ọrọ̀ ajé àwọn ìlú adúláwọ̀, ECOWAS, lórí ìjọba Tiwantiwa àti ìṣèjọba lọ́nà tótọ́  lójú gbangba.”

Ile -iṣẹ ti o n risi ọrọ okeere ni Ilu Naijiria, sọ eleyii di mimọ  ninu alaye kan ti o gbe jade ni ọjọ aiku.

Gẹgẹ bii agbẹnusọ  ile -iṣẹ naa, Iyaafin Esther Sunsuwa, ijọba “bẹnu atẹ lu, ti wọn si kọ jalẹ lori igbajọba lọna aitọ, ti wọn si rọ awọn to wa nidi ifipa gbajọba ọhun lati pẹtu si gbogbo rogbodiyan  naa, laisi idaduro ati ki wọn o si daabo bo ẹmi ati ohun-ini.

A yoo ranti pe, awọn ọmọ -ogun ti o ṣe idagiri ni olu -ilu Guinea ni ọjọ aiku, sọ lori amohunmaworan orilẹ-ede pe, wọn ti tu ijọba orilẹ -ede Iwọ -oorun adulawọ ka ti wọn si tun ti ti gbogbo ilẹ ati awọn aala afẹfẹ.

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.