Take a fresh look at your lifestyle.

Gbogbo pápá ìseré ẹlẹ́kùnjẹkùn tó wà jákè- jádò ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni yóò gba àtúnse – Seyi Makinde

Abiola Ọlọwẹ

0 554

Gomina ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́,Seyi Makinde ti ní gbogbo pápá ìseré ẹlẹ́kùnjẹkùn tó wà jákè- jádò ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni yóò gba àtúnse to mọnyan lórí.

Seyi Makinde sọrọ yii  lasiko ti wọn n síde papa isere Lekan Salami to wa ni agbegbe Adamasigba ni ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni ẹkun gusu iwọ oorun orilẹ ede Naijiria.

igbakeji aarẹ orilẹ ede Naijiria tẹlẹri,, Alhaji Atiku Abubakar wa gbosuba fun gomina  ipinle Oyo, Seyi Makinde  latari atunse ti o se si papa isere Lekan Salami  ọhun.

Alhaji Abubakar eni ti oun ati awọn eekan miran bi i gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu (SAN); gomina ipinle Edo, Godwin Obaseki; gomina ipinle Oyo tẹlẹri, Rasidi Ladoja; Otunba Adebayo Alao-Akala; gomina tẹlẹri alsiko ijoba ologun ni ipinle Oyo, David Jemibewon, eni ti o kọ papa isere ọhun ni ọdun 1976; igbakeji gomina ipinle Oyo, onimo ero Rauf Olaniyan, gbe osuba kare fun gomina Seyi Makinde fun akanse isẹ́ ti o se lati mu idagbasoke ba eré idaraya lasiko ti gomina lọ si papa isere ọhun.

Gomina Seyi Makinde lo side eto ọhun pẹlu ere ifesewonse bọọlu ọlọrẹ-sọrẹ (novelty match), eleyi to waye laarin ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles tẹlẹri ati omo egbe agbabọọlu 3SC tẹlẹri.

Ninu ọrọ rẹ, Alhaji Abubakar jẹ ki o di mimẹ pe oun ti wo kaakiri ilu Ibadan ti oun si le jẹri si isẹ nla ti gomina n se ni pataki julọ ni ẹka idagbasoke ohun amuludun, ti o si gbe osuba kare fun gomina Seyi Makinde.

Ninu ọrọ ọtọọtọ wọn, gomina ipinle Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu ati gomina ipinle Oyo teleri, Otunba Adebayo Alao-Akala naa gbe osuba kare fun gomina Seyi Makinde fun aseyọri nla eleyi ti o se lati mu papa isere Lekan Salami pada bọ sipo

 

.

Ninu eesi rẹ, Makinde fi asiko ohun seleri pe oun yoo sa ipa re lati mu awon papa isere elekunjekun yooku to wa jake jado ipinle Oyo bọ sipo. O wa fi kun un pe, ijoba yoo gbiyanju lati ri daju pe oun se asepari awọn ipele ti o ku ninu papa isere Lekan Salami ohun laipẹ.

Makinde wa dupẹ pupọ lọwọ awọn eniyan rere ipinle Ọyọ ati awọn amugbalẹgbẹ rẹ gbogbo fun atilẹyin ati ifọwọsowọpọ wọn, o si seleri pe oun ko ni jawọn kulẹ labẹ botiwu ko ri.

Lara aọon gbajugbaja agbabọọlu to kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ nibẹ ni a ti ri: Ike Sorunmu, Victor Ikpeba, Taribo West, Felix Owolabi, J.J Okocha, Tijani Babangida, Mutiu Adepoju.

Lara awẹn eekan to peju sibẹ naa ni a ti ri: Oloye Festus Adegboye Onigbinde (akọnimọọngba fun ẹgbẹ agbabọọlu Shooting Stars sports Club ati Nigerian Super Eagles), Igbakeji alaga fun ẹgbẹ oselu PDP ni ẹkun gusu iwọ oorun orilẹ ede Naijiria, Ambassador Taofeek Arapaja, Senator Monsurat Sunmonu, Omooba Olagunsoye Oyinlola.

Awọn ori ade naa ko gbẹyin nibẹ. Lara wọn ni Soun Ogbomoso, Oba Jimoh Oyewumi Ajagungbade; Aseyin ilu Iseyin, oba Abdulganiyu Ajinase Oloogun ebi; Onipetu Ijeru, Oba Sunday Oyediran; Olu ti Igboora, oba Jimoh Olajide Titiloye, nigba ti Alaafin ilu Oyo, Oba Lamidi Adeyemi iii ati Olubadan Ile Ibadan, Oba Saliu Adetunji, Aje Ogungunniso1 ko ri ọ̀nà láti wọlé sibi ayẹyẹ ọhun.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button