Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Bùhárí yọ mínísítà ètò ọ̀gbìn àti mínísítà fún iná mọ̀nà –mọ́ná ńipò

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

147

Ààrẹ Mùhámmádù Bùhárí   kéde àtúntò ráńpẹ́ nínú àwọn  mínísítà rẹ̀, tí èyí sì bá mínísítà mẹ́rin.

Meji ninu awọn mẹrẹẹrin naa ni lati fi ipo silẹ ti meji si lọ di ipo miran mu.

Awọn to yọ nipo ni minisita fun eto ọgbin ati idagbasoke ilu nigba kan ri, Sabo Nanono ati ti ina mọna –mọna,Sale Mamman.

Awọn ti o lọ dipo miran mu ni  minisita fun Ayika tẹlẹ, Muhammad Mahmood Abubakar, ti o gba iṣẹ bayi gẹgẹ bi Minisita fun Iṣẹ -ogbin ati Idagbasoke ilu , ti Minisita  Ipinle fun Awọn Iṣẹ ati ibugbe tẹlẹ, Abubakar Aliyu di Minisita fun ina mọna –mọna.

Oludamọran pataki fun Aarẹ, Femi Adesina ṣalaye eyi fun awọn oniroyin Ile- Ilu ni ipari ipade minisita osẹ naa.

O sọ pe, Aarẹ Buhari ṣeleri pe laipẹ oun yoo wa ẹlomiran si ipo mejii Nanono ati Mamman ti o ṣofo.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.