Take a fresh look at your lifestyle.

Làásìgbò ìpínlẹ̀ Plateau: Ilé-iṣẹ́ ààrẹ pè fún Ìfọ̀kànbalẹ̀

Eyitayọ Oyetunji Fauziat

140

Ààrẹ ti pe gbogbo àwọn agbègbè tí làásìgbò ti ń ṣẹlẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Plateau láti fiyè dénú,  kí wọn sì gba  àlááfìà  láyè ní Ìpínlẹ̀ náà.

Oluranlọwọ pataki fun Aarẹ lori ọrọ iroyin ati Ikede, Garba Shehu pe ipe naa ninu ifiranṣẹ kan ti o gbe jade ni alẹ ọjọ aba mẹta.

Shehu sọ pe, ijọba apapọ n ṣa gbogbo agbara wọn lati  fopin si laasigbo ọhun,lele yi ti o n bani lọkanjẹ.

O sọ pe awọn ti o  pa awọn eniyan ni ilu Jos kii yoo lọ laijiya.

Gẹgẹbi agbẹnusọ aarẹ, o sọ pe ile-iṣẹ aarẹ n mu da gbogbo ara ilu loju pe,gẹgẹ bii ijọba, ohun n ṣe gbogbo akitiyan lati ri pe ọwọ tẹ gbogbo awọn ti wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ aburu to ṣẹlẹ laipẹ ni ipinlẹ Plateau.

Ṣugbọn lati ṣaṣeyọri,iṣeraẹnilọkan gbọdọ wa laarin awọn agbegbe ọhun lati le gbogun ti iwa ibi yii.Ẹsan gbigba kọ ni yoo tan gbogbo nnkan to wa nilẹ wọnyii.
Siwaju si, o rọ awọn aṣaaju ẹsin ati  aṣa lati yago fun itara ninu awọn iṣe wọn, lati le koju ogun naa.

O sọ pe, o ṣe  pataki fun awọn ọmọ orilẹ -ede Naijiria ati agbegbe kariaye lati mọ riri pe, ọpọlọpọ awọn ọna ni wọn n gba lati bori laasigbo ọhun.

 

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.