Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn ọmọ ilé -ìwé Islamiyya tí àwọn ajínigbé kó lọ ti gba òmìnira

128

Àwọn ọmọ ilé -ìwé Islamiyya tí àwọn ajínigbé kó lọ ni ìpínlẹ̀ Niger  ti gba òmìnira ni àsálẹ́ ọjọ́Bọ̀.

oludari ile-iwe ọhun , Alhassan Abubakar lo fidi ọ̀rọ̀ naa mulẹ lasiko ifọrọwerọ pẹlu akọroyin  ile akede Naijiria, Voice of Nigeria lori ẹrọ ibanisọrọ, pe awọn ajinigbe ti fi awọn akẹkọọ  ti wọn ko lọ silẹ.
Amọsa, oludari ile-ẹkọ ọhun ko sọọ boya awọn ajinigbe ọhun  gba owo lọwọ  ijọba ,awọn alaaanu tabi lọwọ awọn obi akẹkọọ ,  ki wọn to tu  awọn akẹkọọ ọhun silẹ.
Mallam Alhassan tun wa sọ pe awọn akẹkọọ ọhun nilo eto  ilera  ni kiakia , nitori pe ipo ti awọn ajinigbe ọhun ti fi wọn si laarin osu mẹta ti wọn ti fi wa ni ahamọ lọdọ wọn.
Ti a o ba gbagbe pe àádóje (130)  awọn akẹkọọ ọhun ni awọn ajinigbe ko lọ ni  adugboTegina ni ijọba ibilẹ rafi ni ipinlẹ Niger ni osu mẹta sẹyin.
Ijọba ipinlẹ Niger ti ni awọn ko san owó fun awọn ajinigbe ọhun , ki awọn akẹkọọ naa to gba ominira lọwọ wọn.
Bakan naa, kọmisọna fun eto iroyin ni ipinlẹ Niger, Mohammed Sani Idris  naa ti gba ominira rẹ lọwọ awọn ajinigbe laisan owo rara , gẹgẹ bi ohun ti o wa ninu atẹjade kan ti wọn gbe sita.
Leave A Reply

Your email address will not be published.