Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Nàíjíríà (NANS) sèlérí láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àjọ EFCC láti dojú ìjà kọ ìwà jàǹdùkú orí ẹ̀rọ ayélujára

Abiọla Ọlọwẹ

139

Àgbárijọ ẹgbẹ́ àwọn  akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàíjíríà (NANS) ti seleri láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹlu àjọ tó ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ àti síse owó ìlú kúmọkùmọ, EFCC  láti dojú ìjà kọ ìwà jàǹdùkú orí ẹ̀rọ ayélujára.

Àgbárijọ ẹgbẹ́ àwọn  akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàíjíríà (NANS) wọnyi lo seleri atilẹyin ohun lasiko ti wọn se abẹwo si ẹkun Ile isẹ ajọ EFCC to kalẹ si agbegbe Iyaganku ni ilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ ni ẹkun gusu iwo oorun orílẹ̀ èdè Nàíjíríà.

Nigba ti o n sọrọ, adari ẹgbẹ́ NANS ẹkun gusu iwọ oorun ‘D’, Kowe Odunayọ fi idunnu rẹ han lori igbiyanju ajọ EFCC lati mu adinku ba iwa janduku orí ẹ̀rọ ayélujára to wa ni ni tibu- toro oorílẹ̀ èdè Nàíjíríà ti o si seleri láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹlu àjọ tó ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ àti síse owó ìlú kúmọkùmọ, EFCC  lọ́nà ati mu adinku ba iwa ibajẹ yii laarin àwọn  akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàíjíríà.

Gẹgẹ bi o se sọ ninu ọrọ rẹ, Kowe jẹ ki o di mimọ pe, niwọn igba ti agbarijọ ẹgbẹ akẹkọọ orilẹ ede Naijiria ti ni igbagbọ ninu isẹ́ ribiribi ti ajọ EFCC n se, pe isẹ́ wa fun awọn lati se, paapaa ni iru asiko bi eyi ti ọgọọrọ ọdọ orilẹ ede yii si n  jinlẹ ninu iwa janduku orí ẹ̀rọ ayélujára.

“Ifọwọsowọpọ pẹlu ajọ EFCC yoo mu adinku ba iwa ibajẹ ati iwa janduku orí ẹ̀rọ ayélujára laarin awọn Ile ẹkọ Fasiti Ilẹ̀ yii”.

Kowe tun salaye siwaju si nigba ti o so pe ẹgbẹ NANS ti n gbero lati se agbekalẹ awọn eto itaniji fun awọn ọdọ jakejado awọn Ile ẹkọ giga orílẹ̀ èdè Nàíjíríà lori ewu to rọ mọ iwa ibajẹ ori ẹrọ ayelujara, ti o si pinnu pe egbe NANS ko ni gba iwa ibajẹ be e laye laarin wọn.

Bakan naa ni Kowe salaye pe ajo NANS ko lodi si ise ti ajo EFCC n se gẹgẹ bi awọn kan se sọ, sugbọn awon nifẹẹ si ise gbigbogun ti iwa ibajẹ ti wọn n se jakejado orílẹ̀ èdè Nàíjíríà ati agbegbe rẹ, ti awẹn si wa se abẹwo yii lati fi ipile ibasepọ to danmọran pelu ajọ EFCC lelẹ.

Eni ti i se adari ajọ EFCC ni ẹkun Ibadan, Kanu Idagu, ti o gba awọn ẹgbẹ́ NANS to wa se abẹwo naa lalejo fi idunnu rẹ han lori anfaani fikunlu’kun to ni pẹlu wọn. O wa salaye pe isẹ nla wa fun wọn lati se, ni eyi lati ge gbongbo iwa ibajẹ kuro ko ma baa di igi alọye lọjọ iwaju.

Kanu wa dupe lowo ẹgbẹ NANS fun abẹwo wọn ati ipinnu wọn lati mu ki iwa ibajẹ di ohun awati lawujọ wa. O si gba wọn niyanju lati sa ipa wọn lati se ohun gbogbo ti wọn seleri ni ọna ati se aseyọri rere.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.