Ìpàdé ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ Ìgbìmọ̀ ìjọba àpapọ̀ kò ní wáyé lọ́sẹ̀ yìí.
Ni deede agogo mẹsan,( deede akoko fun ipade naa), Oniroyin Voice of Nigeria, olu-ilu ṣe akiyesi pe gbangan ti wọn yoo lo fun ipade naa wa ni titiipa.
Akọroyin naa sọ pe, ohun ko ri awọn minisita kankan ati awọn ọmọ igbimọ ijọba apapọ kankan bakannaa, ko kọja si ibukojo aarẹ ni Villa fun ipade naa.Ti kii si ri bẹẹ tẹlẹ.
Awọn alaṣẹ ipade naa, ko ti sọ idi ti wọn fi sun ipade ọhun siwaju.
Sugbọn Isunsiwaju ipade naa le niiṣe pẹlu iṣẹlẹ ibanujẹ ti o waye ni ile-ẹkọ aabo giga Naijiria, ni Kaduna, ni ọjọ Iṣẹgun.
Leave a Reply