Take a fresh look at your lifestyle.

NSIP: Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣàtúnṣe GEEP, tí ó sì tún ṣe ìfilọ́lẹ̀ GEEP 2.0

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

155

Ìjọba orílẹ̀ -èdè Nàìjíríà ti ṣe ìfilọ́lẹ̀  ètò ìṣèránlọ́wọ́ alábọ́dé GEEP 2.0, GEEP 2.0,èyí tí wọ́n ṣàgbékalẹ̀ rẹ̀ láti yá àwọn ènìyàn lówó àti láti kọ́ àwọn ará ìlú tí kò níṣẹ́  ọwọ́ níṣẹ́ lọ́lọ́kan  ọ̀jọ̀kan.

Minisita fun eto ọmọniyan, Isakoso Ajalu ati Idagbasoke Awujọ, Sadiya Umar Farouq lo ṣe ifilọlẹ eto naa ni  Abuja, Naijria.

O sọ pe GEEP 2.0 ẹya atunṣe GEEP, wa fun talaka ti ko lakojọ ati awọn alaini, ṣugbọn to ni oye iṣẹ-ọwọ, ti wọn ko si ni anfaani si awọn eto iyawo ati lati pese iyawo alabọde ati owo ti ko jaralọ fun iṣowo kata kara.

Gẹgẹ bi minisita naa ṣe sọ, wọn  tun ṣagbekalẹ eto naa lati ran awọn alailera,  awọn obinrin ti wọn doju ẹlẹyamẹya kọ, ọdọ alainiṣẹ ati awọn  alaini miiran ni awujọ.

Oluranlọwọ imọ -ẹrọ si Minisita lori GEEP, Zainab Musa Musawa, sọ pe wọn ṣe atunṣe eto naa  lati gbọ tawọn alaini, ti pupọ ninu wọn jẹ obinrin, ọdọ ati awọn agbẹ igberiko .

Oluranlọwọ Imọ -ẹrọ  naa tun sọ siwaju pe, nipasẹ ,itaniji, akojọpọ ati ikopa, awọn oṣiṣẹ wọn yoo pese itọnisọna ati amojuto to munadoko fun gbogbo awọn  to ba  janfani GEEP 2.0.

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.