Take a fresh look at your lifestyle.

Gomina Samuel Ortom kò yẹ nípò adarí òsèlú- Garba Shehu

104

Ijọba apapọ ti bẹnu atẹ lu ọ̀rọ̀ ti gomina ipinlẹ Benue , Samuel Ortom, sọ nipa ẹ̀sùn ti o fi kan aarẹ Buhari pe o n se oju sàájú.

Ninu atẹjade kan ti oluranlọwọ pataki fun aarẹ Buhari lori iroyin ati ikede , Garba Shehu,  ti sọ pe gomina ipinlẹ Benue  ko sẹṣẹ maa sọrọ nipa iwa ẹlẹyamẹya , latari lati lee jẹ ki awọn eniyan fẹna rẹ̀.

Garba Shehu, tun tẹsiwaju pe Ortom ko yẹ nipo adari rara, nipa awọn ọrọ ti ko yẹ ki asiwaju to dipo oselu mu ,maa sọ kaakiri.Idi niyi ti iru eniyan bi Ortom ko yẹ  lati wa nipo oselu lọjọ iwaju.

“iru awọn eniyan gidi, ọmọ ipinlẹ  Benue rere , yẹ ki o ni asiwaju to dara ju iru eniyan bi i Ortom lọ, nitori naa, a n fẹ ki wọn yan eniyan  to dara si ipo oselu ninu eto idibọ to n bọ..”

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.