Take a fresh look at your lifestyle.

òfin epo rọ̀bì àti afẹ́fẹ́ gáàsì yóò mú ìyípadà rere bá ohun àmúsagbára lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà -Osinbajo

99
Igbákejì ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàíjíríà, ọjọgbọn Yemi Osinbajo ti ní ofin ti aarẹ sẹsẹ fọwọsi nipa epo rọbi ati afẹ́fẹ́ gaasi lorilẹ ede Naijiria yoo mu iyipada rere bá ile-isẹ to n pese afẹfẹ gaasi lorilẹ ede Naijiria.
Ọjọgbọn  Osinbajo sọrọ yii lọjọ Aje , nibi idanilẹkọọ ti wọn se lori ẹrọ ayelujara lati fi se ayẹyẹ ọdun karundinlọgbọn  ile isẹ  Sahara to n pese ohun amusagbara.
o tun tẹsiwaju pe ofin tuntun  ọhun yoo tun jẹ ki awọn olokoowo lee da ile-isẹ epo rọbi silẹ lorilẹ ede Naijiria.Bakan naa , ni wọn yoo tun ri i pe lilo afẹfẹ gaasi fun ọkọ ayọkẹlẹ dipo epo rọbi waye lorilẹ ede Naijiria.
Igbakeji aarẹ tun sọ pe ni ọdun marundinlọgbọn to n bọ , yoo tun jẹ ki idagbasoke ba ipese afẹfẹ gaasi lorilẹ ede Naijiria.
lara awọn to sọrọ nibi ayẹyẹ ọhun ni  aarẹ orilẹ ede Congo, ọgbẹni  Felix Tshisekedi ati aarẹ  ile -ifowopamọ ti ilẹ Afirika , African Development Bank, ọmọwe Akinwumi Adesina; ati awọn oludari ile-isẹ aladaani ati ti ijọba.
Leave A Reply

Your email address will not be published.