Orílè -èdè Nàìjíríà ṣe ìrántí àyájọ́ ọjọ́ òwò ẹrú jákèjádò Àgbáyé àti Ìparun rẹ̀.
Eyitayọ Eyitayọ Oyetunji
Lónìí, Nàìjíríà yóò darapọ̀ mọ́ gbogbo àgbáyé láti ṣe ìrántí àyájọ́ ọjọ́ òwò ẹrú ọlọ́dọọdún àti ìparun rẹ̀.
Akori ti ayẹyẹ ọdun yii ni “ẹru ode-oni, Ibeere lapapọ: Idaabobo Ọjọ Ọla”
Ayẹyẹ naa, eyiti wọn ṣeto lati bẹrẹ ni deede agogo mẹsan owurọ, ni ibudo awọn akọroyin ti Orilẹ -ede, ni Ile- asọrọmagbẹsi, olugbalejo eto naa ni, Ile -iṣẹ apapọ fun iroyin ati Aṣa pẹlu ifọwọsowọpọ awọn ile-iṣẹ abẹ rẹ, UNESCO ati awọn alabaṣepọ miiran.
Olugbalẹjo ọjọ naa ni, Minisita fun iroyin ati Asa, Alhaji Lai Mohammed.
Ayẹyẹ Ọjọ ayajọ fun Iranti Iṣowo Ẹrú ati Iparun rẹ jakejado agbaye maa n waye ni ọjọ kẹtale-logun, Oṣu Kẹjọ ọdọọdun , ọjọ ti UNESCO ya sọtọ fun iranti isowo ẹrú oke-okun.
Leave a Reply