Take a fresh look at your lifestyle.

Ènìyàn mééjìlá- dín -nírínwó míràn tún ti ní ààrùn covid

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

65

Àwọn ènìyàn mééjìlá-dín-nírínwó míràn tún ti ní ààrùn covid ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ile-iṣẹ to n mojuto ajakalẹ aarun ni orilẹ-ede NCDC,lo fidiẹ mulẹ ni alẹ ọjọ aiku, lori ayelujara wẹẹbu rẹ.

NCDC tun pe akiyesi si pe, awọn eniyan mẹjọ  si jẹpe ọlọrun nipase aarun covid bakannaa.

Ile-iṣẹ naa sọ pe, awọn eniyan mejila-din-nirinwo ọhun jẹ yọ lati ipinlẹ mejila- Lagos (mẹrin-din-lọgọjọ),Akwa Ibom (mọkan-din-laadọrun ),Rivers (mẹrin-din-lọgọrin) ,Ọyọ (mẹẹdogun) ,Ẹdo (mejila),Benue (mọkanla),Delta (meje) ,FCT (mẹrin),Ogun (mẹrin) ,Kaduna (meji), Gombe (ẹyọkan), Nasarawa (ẹyọkan).

Lọwọlọwọ bayii, eniyan mẹ̀ẹ́dẹ́gbàrin- le- ni- ọ̀kẹ́ mẹ̀sán – le ni- ẹ̀ta- le ni- okòó lo ti ni aarun naa,eniyan ẹgbàárin- le ni- ọ̀kẹ́ mẹ̀jọ – le ni- ẹ́ẹdógún-din-ni-ọ́ta- din- ni- ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́ta ti gba iwosan,ti eniyan mèjì-le-ni-ojì din- ni- ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́éjìlá si ti jẹpe oluwa.

Leave A Reply

Your email address will not be published.