Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ sọ́ra fún ìwà ìlòkulò oògùn nítorí ìpalára rẹ̀ láwùjọ- Aṣofin Sanni Ganiyu Okanlawon

Lanre Lagada-Abayọmi

86

Aṣofin  Sanni Ganiyu Okanlawon, ti o n ṣoju ekun Koṣofẹ kinni ninu  Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko ti rọ awọn obi, alagbatọ awọn olori ẹlẹsin ati awọn tọrọ kan gbogbo  lati ṣojuṣe wọn nipa mimojuto awọn ọmọ, bi ljọba naa ti n sapa tirẹ. O sọrọ yii nibi Ipade Alẹnulọrọ Ọlọdọọdun, eyi ti Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko maa n ṣagbatẹru kaakiri awọn ẹkun idibo ogoji si Ile Igbimọ Aṣofin naa ni Ipinlẹ Eko, lati fun awọn ara ilu lanfaani fifi ẹdun ọkan wọn han lori idagbasoke ilu. Ẹlẹẹkeje iru rẹ ni ti ẹkun Koṣọfẹ kiini waye ni Gbongan ilu Mende lagbegbe Maryland ni Ipinlẹ Eko.

Nigba ti o n sọrọ lori akoonu tọdun yii, “Bi Iwa Ilokulo Oogun ṣe n pọ sii n ṣe akoba fun idagbasoke orilẹ-ede yii” Aṣofin Ọkanlawọn ṣe kilọkilọ pe bi wọn ko ba tete moju to iwa yii, o ṣẹṣẹ ki o ṣakoba nla fun idagbasoke ilu ati ọrọ-aje.

O tẹnu mọ pe awọn obi ni lati ṣojuṣe wọn nipa mimojuto awọn ọmọ, bi ljọba naa ti n sapa tirẹ. O mẹnu ba awọn igbesẹ ijọba Ipinlẹ Eko paapaa Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko lati ṣadinku iwa ilokulo oogun ati lilo oogun oloro lawujọ. Ọpọ awọn ofin ati ipinnu ni Ile Aṣofin naa ti fọwọ si lati fi ṣadinku iwa buruku, eyi ti awọn ọdo yoo fi le maa gbe igbesi aye irọrun. O ni

“Ile Igbimọ Aṣofin yii n gbiyanju lati ṣe awọn ofin ati ilana ti yoo mu idagbasoke ba igbe aye awọn ọdọ wa. Ọpọ ni awọn awọn ofin to ti wa nilẹ ti o le jẹrii si eyi, lara rẹ ni “Ofin Ṣiṣe atunṣẹ Igbimọ Alakoso Ere Idaraya ni Ipinlẹ Eko ti ọdun 2015 lati mu Igberu ba Igbe aye awọn ọdọ ati Ere Idaraya ni Ipinlẹ Eko, pẹlu awọn nnkan miiran to jẹ mọ ọn.”

Aṣofin Ọkanlawọn tun ṣalaye pe awọn abadofin miiran tun n lọ lọwọ lati tubọ fi mu idagbasoke ba awọn ọdọ ni Ipinlẹ Eko. O ni:

“Awọn abadofin miiran wa ti wọn n jiroro le lori ninu Ile bayii, ti atunbọtan rẹ yoo ṣanfaani fun awọn ọdọ bii ”Abadofin fun Pipese fun Idasilẹ Ile-ẹkọ Fafiti fun Eto Ẹkọ ni Ipinlẹ Eko ati awọn nnkan miiran to jẹ mọ ọn.” Eleyii yoo maa kọ awọn ẹkọ to nii ṣe pẹlu eto ẹkọ, ti wọn yoo maa gba awọn iwe ẹri loroṣiiriṣi lati ibẹ. Omiran ni “Abadofin ṣiṣe idasilẹ  Fafiti Ipinlẹ Eko fun ẹkọ Sayẹnsi ati Imọ-ẹrọ”

Ninu ọrọ ikini kaabọ ọjọ naa, Alaga fun ẹgbẹ oṣelu of All Progressives Congress (APC) ni Agbegbe Ijọba Ibilẹ Koṣofẹ, Ọgbẹni Kehinde Bello, fi mulẹ pe akoonu Ipade Awọn Alẹnulọrọ tọdun yii ṣe pataki lasiko yii, ki a le foju sunnukun wa ojutu si ipalara iwa ilokulo oogun yii, eleyii to ti n ṣakoba nla fun awọn ọdọ ode oni. O ni awọn akopa yoo le ri ẹkọ mu kuro nibi ipade yii, paapaa pẹlu akoonu naa.

Agba Oṣelu kan, ti o jẹ ọmọ Igbimọ Alaṣẹ agba ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ni Ipinlẹ Eko, Ọmọọba Olumuyiwa Ṣosanya rọ awọn tọrọ kan gbogbo lati gbaruku ti amojuto awọn ọmọde ati ọdọ paapaa bi iwa ilokulo oogun ṣe n peleke si i lasiko yii lorilẹ-ede Naijiria. O fi ọrọ yii bu ẹnu atẹ lu ipalara ti iwa yii n fa lawujọ ti o si n gbẹmi ọpọ eniyan loorekoore. O ni atunbọtan iwa yii ti n ṣe ipalara fun ọrọ-aje ati idagbasoke ilu. O ni:

“Ọpọ awọn obi ati alagbatọ kan lo wa ti awọn ọmọ wọn n lo oogun oloro ti wọn ko le ba wọn wi. Tẹẹ ba le ba wọn wi, ẹ pe awọn agbalagba ti wọn le ṣe eyi. Nitori awọn ọmọde yii ro pe bi awọn ba mu oogun yii, o maa n fun awọn ni igboya, ṣugbọn ipalara nla lo n jẹ ni igbẹyin. Fun idi eyi awọn obi ni lati moju to awọn ọmọ wọnyi, lati le dekun iwa ilokulo oogun yii.”  

Oludanilẹkọọ pataki ọjọ naa, Arabinrin Ngozi Okocha, oga kan lati Ajọ to n gbogun ti ilokulo oogun lorilẹ-ede Naijiria, iyẹn National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA), ninu apilẹkọ rẹ, ṣe kilọkilọ pe bi wọn ko ba tete moju to ilokulo oogun lorilẹ-ede yii bayii, yoo ṣe ipalara pupọ fun awujọ. O tẹnu mọ pe bi awọn to n lo ilokulo oogun ati oogun oloro ṣe n pọ bayii jẹ ohun iyanu ti awujọ gbọdọ tete wa nnkan ṣe si i. Nitori eyi ṣeeṣe ko ba igbesi aye awọn ọdọ ode oni jẹ. Ninu akori naa, pẹlu abala ti wọn pe ni, Bi Lilo oogun ti ko tọ ati Aṣilo oogun ṣe n peleke si, yoo ṣakoba nla fun Idagbasoke Awujọ”, oludanilẹkọọ naa sọ pe bi awọn ọdọ ṣe n lọwọ ninu  ilokulo oogun ati oogun oloro lorilẹ-ede Naijiria ti n ṣe ni kayefi. O ni:

“O le ni miliọọnu mẹrin awọn eniyan ni orilẹ-ede Naijiria ti wọn n lo oogun loriṣiiriṣi ni ọdun 2020. Iwadii ti fi han pe iko mọkanla ninu ida ọgọrun-un ni alekun awọn ti o n ṣi oogun lo yoo jẹ ni ọdun 2030 lagbayee. Iko ogoji bayii ni yoo wa ni ilẹ Afirika ti wọn ko ba tete dẹkun rẹ bayii.”

Arabinrin  Okocha sọ pe iwa yii ti n ṣakoba fun idagbasoke awujọ bayii, paapaa ti awọn ohun eelo ilu bi ẹwọn ati ile-ẹjọ n kun akunfaya latari awọn ẹsun to nii ṣe pẹlu oogun oloro ati atubọtan rẹ, ti o si ni ipa buruku lara aabo orilẹ-ede ati ilera awọn ara ilu.

O wa rọ awọn ara ilu lati maa ṣọ awọn ti oogun oloro ba se ipalara fun ki wọn le tọju wọn nitori ajọ to n gbogun ti ilokulo oogun n pese eto ati ṣe itọju iru awọn eniyan yii.

Oludanilẹkọọ miiran lori koko ọrọ yii kan naa, Dokita Fatima Binta Amodu, ti o jẹ oniṣ̣egun oyinbo lati Fafiti Redeemers, yan-na-an-na ohun ti a n pe ni ilokulo oogun. O ni ki i ṣe lilo oogun oloro nikan ni iwa aṣilo oogun, ṣugbọn ti a ko ba lo oogun gẹgẹ bi oloogun oyinbo ṣe sọ pe ki a lo, tabi lo o lọna to wu wa, gbogbo eyi ni ilokulo oogun. O ni:

“Bi eniyan ba kan lo kikida  ‘paracetamol, tabi awọn oogun ikọ lọna ti ko tọ, o ṣeeṣe ko ṣe ipalara fun ilera ẹda. Fun bi apẹẹrẹ, bi alaboyun ba lo oogun ‘parcetamol’ nilokulo, o le sọ ọmọ inu rẹ di didinrin bo ba bi i Fun idi eyi, ọpọ ọna ni awọn eniyan fi n ṣi oogun lo” 

O wa rọ awọn obi ati alagbaọọ lati maa ṣọ awọn iwa ti awọn ọmọ wọn ba n wu.

Dokita Basirat Giwa, oniṣegun oyinbo kan ti oun naa sọrọ nibi pade itagangba yii dẹbi iwa buruku yii ru ẹbi, awujọ ati ijọba. Ni ti ẹbi paapaa awọn iya, o ni ọpọ ni ki i bikita nipa awọn ọmọ wọn paapaa  awọn ọmọkunrin. Obi yẹ ki wọn maa lọ si ile-ẹkọ awọn ọmọ wọn lati lọ maa wo bi wọn ṣe n ṣe si deedee. Ni ti awujọ, o ni o yẹ ki awọn agbaagba si maa ni iwa “oju meji lo n bimọ, igba oju lo n tọ.” Ki awọn ara adugbo maa foju silẹ lati maa wo bi awọn ọmọde ṣe n ṣe, eyi ti wọn yoo fi maa tọ wọn sọna to yẹ, nitori, bi a ba ni ko kan wa, awujọ ni yoo jiya atubọtan iwa ilokulo oogun yii. Ẹwẹ, ni ti ijọba, o rọ awọn alaṣẹ lati ṣe idasilẹ ọpọ awọn gbagede iṣere idaraya, ti awọn ọdọ yoo le maa ṣamulo bi wọn ko ba tilẹ ti p ni iṣẹ lọwọ, nitori ọwọ to ba dilẹ ni eṣu n bẹ lọwẹ

Ọpọ awọn ti wọn tun fẹnu si ọrọ yii ni awọn aṣoju lati ijọ ẹlẹsin, ẹgbẹ awọn ọlọja, ẹgbẹ awọn akanda ẹda ati bẹẹ bẹ lọ ti wọn wa lati ẹkun Koṣọfẹ kiini yii. Gbogbo wọn lo bẹnu atẹ lu iwa ilokulo oogun lawujọ, ati pe awujọ gbọdọ tete gbe igbesẹ lati dẹkun rẹ, ki o to ṣakoba fun idagbasoke awujọ patapata.

Sibẹ awọn ara ilu ko ṣai fẹmi imoore han si awọn ohun ti ijọba ti ṣe fun wọn gẹgẹ bi ara ibeere wọn ninu ipade alẹnulọrọ yii lọdun to kọja. Lara awọn aṣeyori naa gẹgẹ bi Aṣofin Ọkanlawọn Sanni ṣe mẹnu ba a ni ‘ṣiṣe ọna adugbo Ọlabisi, ọna adugbo  Ilajẹ ati ọna Kujọre ni Ogudu ati ọna Oworonshoki. Omiran ni ṣiṣe atuṣe si awọn ile ẹko girama bii ‘Muslim High School ni Oworonshoki, Ojota Senior High School’ ati awọn miiran bẹẹ ti wọn si kọ akọkun ile-ikẹkọọ mejidinlogun si ọkọọkan. Bẹẹ ni aṣofin yii tun ṣe idasilẹ gbọngan ere idaraya gbigba ẹyin lori tabili, iyẹn ‘table tennis academy’ ati eto ẹyawo alabọde fun awọn opo at awọn ọlọja.’.

Ẹwẹ, awọn akopa kan dide lati fi iwe igbọraẹni ye lori awọn ibeere wọn fun idagbsoke ilu ṣọwọ si aṣofin naa. Bakan naa ni Aṣofin Ọkanlawọn Sanni rọ awọn to ku lati fi ti wọn naa ṣowọ si ofiisi rẹ. O si tun ṣe ileri ṣiṣe eto ironi-lagbara pataki fun awọn ara ilu ninu oṣu kewaa si oṣu kọkanla ọdun yii

Lara awọn eniyan pataki ti o tun wa nibi Ipade Awọn Alẹnulọrọ yii ni Alaga agbegbe Ijọba Ibilẹ Koṣọfrẹ, Ọgbẹni Mọyọsore Ogunlẹwẹ ati Igbakeji rẹ, Ọgbẹni Saliu, awọn aṣoju Ọba Oworonshoki ati Ọba Ojodu ati awọn Baalẹ.

Leave A Reply

Your email address will not be published.