Ààrẹ Bùhárí ṣèdárò oloogbe ìyá-ààfin Victoria Aguyi-Ironsi ìyàwó ààrẹ àkọ́kọ́ fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ààrẹ Mùhámmádù Bùhárí ti bá ìdílé Aguiyi-Ironsi, ìjọba àti àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ábiá kẹ́dùn lórí ikú Olóyè Ìyáàfin Victoria Aguiyi-Ironsi,ẹni tí ó jẹ́ ìyàwó Olórí ìjọba àpapọ̀ àkọ́kọ́, ajagun Johnson Thomas Aguiyi-Ironsi.
Ninu ifiranṣẹ kan, aarẹ mu daniloju pe, iya-afin Victoria jẹ eniyan takuntakun ti ko lẹgbẹ,oniigboya ti ko labawọn, lasiko ọkan ninu awọn akoko tokunkun ṣu ribiribi julọ ninu itan Naijiria,ti eyi si fihan gbangba pe, iya orilẹ-ede ni, ẹni ti o nibẹru Ọlọrun ati ti o si tun jẹ obinrin akọni akọkọ ni.
Aarẹ sọ pe, ọdun marun –din-lọgọta lẹhin iku ọkọ rọ ajagun J.T Aguiyi-Ironsi, Arabinrin Victoria ko da ọwọ iṣẹ ribiribi to n ṣe duro ni orilẹ-ede Naijiria, fun alaafia, iduroṣinṣin, imularada ati ilaja.
Alakoso n fi tọkàntọkàn ṣadura pe,ilakaka iya-afin Victoria fun orilẹ -ede kii yoo ja sasan, ati pe ohun darapọ mọ gbogbo awọn ọmọ orilẹ -ede Naijiria ni gbigbadura fun isinmi ẹmi rẹ,ati ki ọlọrun ki o tẹ safẹfẹ rere.
Leave a Reply