Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Bùhárí ṣèdárò oloogbe ìyá-ààfin Victoria Aguyi-Ironsi ìyàwó ààrẹ àkọ́kọ́ fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

77

Ààrẹ Mùhámmádù Bùhárí ti bá ìdílé Aguiyi-Ironsi, ìjọba àti àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ábiá kẹ́dùn lórí ikú Olóyè Ìyáàfin Victoria Aguiyi-Ironsi,ẹni tí ó jẹ́  ìyàwó Olórí ìjọba àpapọ̀ àkọ́kọ́, ajagun Johnson Thomas Aguiyi-Ironsi.

Ninu ifiranṣẹ kan, aarẹ mu daniloju pe, iya-afin Victoria jẹ eniyan takuntakun  ti ko lẹgbẹ,oniigboya ti ko labawọn, lasiko ọkan ninu awọn akoko tokunkun ṣu ribiribi julọ ninu itan Naijiria,ti eyi si fihan gbangba pe,   iya  orilẹ-ede ni, ẹni ti o nibẹru Ọlọrun ati ti o si tun jẹ obinrin  akọni akọkọ ni.

Aarẹ sọ pe, ọdun marun –din-lọgọta lẹhin iku ọkọ rọ  ajagun J.T Aguiyi-Ironsi, Arabinrin Victoria ko da ọwọ iṣẹ ribiribi to n ṣe duro ni orilẹ-ede Naijiria,  fun alaafia, iduroṣinṣin, imularada ati ilaja.

Alakoso n fi tọkàntọkàn  ṣadura pe,ilakaka  iya-afin Victoria fun orilẹ -ede  kii yoo ja sasan, ati pe ohun darapọ mọ gbogbo awọn ọmọ orilẹ -ede Naijiria ni gbigbadura fun isinmi ẹmi rẹ,ati ki ọlọrun ki o tẹ safẹfẹ rere.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.