Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ́rin ènìyàn ti kó àrùn onígbá-méjì ni orilẹ ede Niger

Ademọla Adepọju

69

Orílẹ̀-èdè Niger ń dojúkọ àjàkálẹ̀ àrùn onígbá-méjì nípasẹ̀ àwọn omíyalé latari  àwọn òjò ńlá- ńlá tó ń rọ̀ lọ́wọ́ káakiri àgbáyé, tó sì jẹ́ pé ẹgbẹ́rin àwọn ènìyàn ló ti kó àrùn náà ní orílẹ̀-èdè ìwọ̀ orùn ní ilẹ̀ Afirika.

Gẹgẹ bi Minisita fun eto Ilera ti Orilẹ-ede ọhun , Dokita Idi Illiassou Mainassanara, se sọ pe arun yii ti jẹ ki atunse wa lori eto ilera, eyi si jẹ ki atunse wa lori ajakalẹ arun naa.

Olori gbogbo Dokita ti agbegbe ile-iwosan Niamey kẹta, Dokita habou abdourahamane, sọ pe ki gbogbo awọn ẹka ile-iwosan orilẹ-ede wa ni igbaradi fun ajakalẹ arun onígbá-méjì naa, ki gbogbo ile-iwosan naa si se idanilẹkọ fun gbogbo oṣiṣẹ wọn lori ilana ilera, paapaa lori arun onígbá-méjì ki wọn si pese gbogbo awọn nnkan ti wọn ba nilo lati fi da arun naa duro.

Abule Gabagoura ni orilẹ ede Niger ni ibiti àgbàrá òjò ti san ju ni Orilẹ-ede ni ọjọ kọkanla, Osu Kejọ, ti Minisita fun eto ilera si ti seto ikọ eleto ilera lati maa sisẹ ni awọn agbegbe naa, ki wọn  si maa se abojuto awọn alaisan agbegbe naa, O si tun kọ awọn ti wọn n gbe ni agbegbe naa bi wọn yo se ma se ìmọ́tótó.

 

 

 

 

 

Damola ati Kehinde

Leave A Reply

Your email address will not be published.