Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Nàíjíríà, ẹ lo owó tí ẹ bá yá fún ìdàgbàsókè ètò okoòwò – Peter Obi

111

Gomina ìpínlẹ̀ Anambra tẹ́lẹ̀rih , Peter Obi, ti rọ ìjọba orílẹ̀ èdè Nàíjíríà láti máa lo owó tí wọ́n bá yá fún ìdàgbàsókè  ètò okoòwò lórílẹ̀ èdè Nàíjíríà.

Obi,  tẹsiwaju pe, kii se nnkan buruku ni ki orilẹ ede kan yawo  sugbọn ti orilẹ ede naa ba kunna lati lo owó ọhun fun eto idagbasoke okoowo , ni o buru julọ.

oludije fun igbakeji aarẹ fun ẹgbẹ́ oselu,Peoples Democratic Party (PDP) sọ̀rọ̀  yii lọjọ Ẹti lasiko to n dahun ibeere awọn akọroyin nigba  to  dari ikọ̀ igbimọ fafiti ti  Dominican lọ si ile-isẹ  Seyi Makinde tó jẹ́ gomina ipinlẹ Oyo to wa ni  Agodi, Ibadan.

O tẹsiwaju pe : “Ti a ba yawo fun oúnjẹ , eyi buru julọ fun orilẹ ede Naijiria.Wọn sọ pe awọn yawo fun eto okoowo , mo si beere pe nibo ni eto okoowo naa wa.Ti wọn ba lo owó ti wọn ya wọnyi fún idagbasoke eto okoowo, eto okoowo orilẹ ede Naijiria yoo ti  dara ju bayii lọ, sugbọn eto okoowo Naijiria ń jó i-jó-àjórẹ̀yìn .o yẹ ki a yawo fun idagbasoke eto ẹ̀kọ́, eto ilera ati lati yọ awọn eniyan kuro ninu òsì.”

Gomina  Seyi Makinde wa sọrọ idaniju fun awọn ikọ naa pe, oun ko ni kaarẹ lati ri i pe eto idagbasoke ba eto okoowo ati ọrọ̀ ajé ni ipinlẹ Ọyọ, o tun tẹsiwaju pe awọn yoo tun gbiyanju lati ri i pe awọn baalu yoo tun pọ si lati maa gbera lati ilu Ibadan lọ si awọn ilu miran ni orilẹ ede ede Naijiria.

Eto ẹ̀kọ́
Makinde  tun sọ pe ijọba oun yooo fọwọsowọpọ  pẹlu  Fafiti  Dominican  fun idagbasoke  eto ẹkọ ni ipinlẹ Ọyọ.

O tun wa seleri  lati foju lamẹẹtọ wo ohun ti Fafiti naa n beere nipa ilẹ̀ ti ijọba  gba lọwọ wọn , ni eyi ti wọn  lo fun  isẹ́ àkànse ọkọ oju irin  Eko sí Ibadan.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.