Take a fresh look at your lifestyle.

Nàìjíríà yóò ya Ọjọ́ kan sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ àyájọ́ Fún Àwọn Àgbàlagbà Láìpẹ́ -–Mínísítà

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 177

Mínísítà fún ètò ọmọnìyàn, gbígbógun ti Àjálù àti Ìdàgbàsókè Àwùjọ, Hájìyá Sàdíyá Umar Farouq, ti fidánilójú pé, wọ́n yóò kéde yíya ọjọ́ kan pátákí sọ́tọ̀ fún àwọn àgbàlagbà láìpẹ́.

Farouq mu eleyi daniloju nigba ti ikọ̀ àjọ ẹgbẹ  to n ṣakoso awọn ọmọ ilu  ti o jẹ agbalagba ni orilẹ-ede Naijiria  (NSCC) ti oludari gbogbogbo ,  Emem Omokaro dari rẹ, ṣe abẹwo si  ni ilu Abuja.

ṣaaju eyi ni, Omokaro bẹbẹ fun ikede ọjọ ayajọ kan fun awọn agbalagba ni Naijiria, laarin  Oṣu Kẹjọ ati ibẹrẹ Oṣu Kẹsan ọdun 2021, lati ṣe ayẹyẹ ayajọ Ọjọ  awọn agbalagba fun igba akọkọ ni Oṣu Kẹwa ọdun 2021.

O tun n beere fun iranlọwọ  NSCC lati fun awọn ọmọ ilu to jẹ agbalagba(SCN) ti o ba ti ju  aadọrin ọdun lọ lati   ṣe iforukọsilẹ ti Orilẹ -ede.

O sọ bakan naa pe, eleyi yoo  fun wọn ni idanimọ ti o munadoko, awọn iṣẹ ti o ba  ọjọ -ori mu ati iṣadehun awọn  ile -ifowopamọ ati awọn ohun elo, opopona, afẹfẹ ati awọn iṣẹ  ọkọ oju –irin, ilera ati awọn iṣẹ ile -iwosan.

Abayọri pataki  abẹwo naa ni,  sise   atẹjade ti wọn  fi sita ni ipari ijiroro ọlọjọ kan fun awọn agbalagba  alakọkọ rẹ, ti   ajọ to n mojuto awọn ara  agbalagba ni Orilẹ-ede gbe kalẹ ni ọjọ kẹta,Oṣu Kẹjọ.

Ijọba apapọ fi ontẹ lu ajọ ọhun ni Orilẹ -ede, ti wọn ṣe ifilọlẹ rẹ ni Oṣu Karun un.

 

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.