Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Nàìjíríà ṣe ìlérí pé òhun yóò jẹ́ kí abẹ́rẹ́ àjẹsára covid wà lárọ̀wọ́tó

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

49

Ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ṣe ìlérí láti ríi dájú pé  abẹ́rẹ́ àjẹsára covid wà lọ́pọ̀ yanturu jákèjádò orílẹ̀-èdè náà.

Akọwe  ijọba apapọ ati alaga,igbimọ alakoso aarẹ lori aarun covid,Boss Mustapha,fidi eyi mulẹ nibi ifilọlẹ abala kinni abẹrẹ ajẹsara covid ,ni ilu Abuja.

O sọ pe Igbimọ aarẹ to n mojuto arun COVID-19 yoo tẹsiwaju lati ṣe abojuto bii aarun covid-19  ṣe n gbalẹ̀ si i,ni orilẹ-ede ti aarun ọhun ti pọju ti o si n tan kaakiri.

O ṣe akiyesi pe ẹni-kọọkan  ni o ni ojuṣe lati daabobo ilera awọn eniyan wọn, nipa ṣiṣe idaniloju pe gbogbo awọn eniyan ti o yẹ ni ile wọn ati  agbegbe wọn gba abẹrẹ  ajesara covid, lakoko ti ijọba yoo tẹsiwaju lati rii daju pe abẹrẹ ajesara naa wa lọpọ yanturu.

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.