Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kí ààrẹ orílẹ-èdè Zambia tí wọ́n dìbò yàn kú oríire

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

69

Ààrẹ Mùhámmádù Bùhárí  kí Ààrẹ orílẹ̀-èdè Zambia, Hakainde Hichilema kú oríire lórí àṣeyọrí rẹ̀ nínú ìdìbò ààrẹ, ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹjọ, ọdún 2021.

Aarẹ gbe oriyin fun awọn ọmọ orilẹ-ede naa bi wọn ṣe tu yaya,ti wọn tu yaya lati ṣe ojuṣe wọn gẹgẹ bii ara ilu,nipa yiyan oludije ti wọn yan laayo,leyi ti o  fihan  daju  pe iṣọkan,iduroṣinṣin ati ilọsiwaju adulawọ wa ninu, agbara ti awọn eniyan ni lati yan oludari wọn pẹlu irọrun.

Aarẹ Buhari tun gboriyin fun aarẹ Edgar Lungu fun gbigba abajade idibo ati  gbigbe ijọba kalẹ  ni alaafia, ti o si pe  akiyesi si iru ihuwasi  bayii gegẹ bii awokọṣe fun gbogbo ololufẹ ijọba tiwantiwa.

Nigba ti o  n ṣapejuwe itan  ati ajọṣepọ ti o wa laarin Naijiria ati Zambia, aarẹ orilẹ-ede Naijiria nireti lati ṣiṣẹ ni pẹkinpẹki pẹlu Aarẹ Zambia ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan fun alaafia, idagbasoke ati ilọsiwaju awọn orilẹ-ede mejeeji.

Leave A Reply

Your email address will not be published.