Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Buhari padà ṣí ìlú Abuja lẹ́yìn ìpàdé àpérò ètò ẹ̀kọ́ tí ó se ní London

143

Aarẹ Muhammadu Buhari ti pada si ilu Abuja lẹyin ipade apero ti o se lati darapọmọ awọn adari orilẹ ede ni London , ní United Kingdom lati jiroro lori bi eto idagbasoke yoo se de ba ètò ẹ̀kọ́ lorilẹ ede wọn.

Aarẹ Buhari de si orilẹ ede Naijiria ni irọlẹ  ọjọ Ẹti si papa ọkọ ofurufu  ti aarẹ to wa ni  Nnamdi Azikiwe pẹlu adari osisẹ aarẹ , ọjọgbọn Ibrahim Gambari, Minisita fun ilu , Abuja,Federal Capital Territory (FCT), Malam Muhammed Bello,pẹlu awọn adari ile-isẹ to n mojuto eto aabo lorilẹ ede Naijriia.ati awọn osisẹ ijọba aarẹ Buhari.

Lasiko ti aarẹ Buhari wa ni London , o lo anfaani ọhun lati se ayẹwo ilera rẹ.

Bakan naa, ni aarẹ Buhari seleri lati mu eto idagbasoke lọkunkundun lorilẹ ede Naijiria nipa sise afikun si eto isuna owó fún eto ẹkọ  pẹlu ilọpo meji laarin ọdun meji .

Leave A Reply

Your email address will not be published.