Take a fresh look at your lifestyle.

Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ò le túká – Garba Shehu

Ademọ̀la Adepọju

110

Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún Aarẹ Muhammadu Buhari fun iroyin ati ikede,  Malam  Garba Shehu ti rọ àwọn ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti fọwọsọwọ́pọ̀ fún ìgbéga àti ìdàgbàsókè Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Garba Shehu sọrọ yii níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ ọdọọdún àti ayẹyẹ ẹ̀bùn àwọn oníròyìn  ní Ọdún 2021 ní Ìlú Abuja.

Minisita fun eto irinna ọkọ oju ofurufu tẹlẹri lorilẹ ede Naijiria , Fani Kayode salaye pe Orilẹ-ede Naijiria nilo ọkunrin  ti gbogbo awọn ọmọ orilẹ-ede le jẹri  pe o se e fọkanti lati le jẹ aare lọdun 2023.

igbakeji oludari ile igbimọ asofin fun ẹgbẹ to kere julọ , Emmanuel Bwacha ti o bẹrẹ eto  ariyanjiyan  naa se salaye ọna lati yanju rogbodiyan tabi aiyede to wa lorile-ede.

Alukoro  ti awọn oniroyin Kwararafa, Ọgbẹni Emmanuel Bello sọ pe sise iṣaro-ọrọ lori awọn iwa ibajẹ to wa lorilẹ-ede  Naijria yoo se iranlọwọ pupọ fun Orilẹ-ede lati le dẹkun awọn iwa ibajẹ to n daa Orilẹ-ede laamu.

Gomina  Ipinlẹ Kogi, Bello Yahya, Minisita fun Ina Mọnamọna, Engr. Saleh Mamman ati asofin  Emmanuel Bwacha wa lara awọn to gba aami-ẹyẹ awọn oniroyin.

 

 

 

 

Hamzat Damola

Leave A Reply

Your email address will not be published.