Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ̀yin dókítà , a ò dún ìkookò mọ́ọ yín láti padà sẹ́nu isẹ́, sùgbọ́n ètò ò sisẹ́, kò sówó jẹ́ òfin àjọ àgbáyé- Osagie Ehanire

92

Minisita fun eto ilera lorilẹ ede Naijiria, Osagie Ehanire ti ni ahesọ ọrọ ni pe ijọba n dun ìkookò mọ awọn ẹgbẹ awọn  dokita  to n se itọju abẹle  to n yan isẹlodi lati pada sẹnu isẹ́ wọn.

Minista fun eto ilera  lo sọrọ yii pẹlu awọn akọroyin niluu Abuja.O wa tun rọ awọn dokita lati pada sẹnu isẹ́ wọn ni iyanju lati gbogun ti arun COVID-19 to wa lorilẹ ede Naijiria.

Ehanire sọ pe: “Ti a ba n sọrọ nipa iyansẹlodi, ki i se asiko yii lo yẹ ki awọn dokita bẹrẹ iyansẹlodi wọn.Ẹlẹẹkẹta niyi, ti awọn dokita maa da isẹ́ silẹ lorilẹ ede yii, ni eyi ti ko bojumo tó.

“A ti rọ awọn dokita abẹle , a ti n se ipade pẹlu wọn  lati maa sọ fun wọn pe , wọn ni ojuse lati se fun orilẹ ede wọn.Gbogbo orilẹ ede to n koju ipenija , lo yẹ ko mọ pe ojuse wọn ni lati ran orilẹ ede wọn lọwọ.Ti o ba ni isoro tabi ikunsinu kan , ti a o ba lee yanju rẹ bayii, ẹ jẹ ki a tẹsiwaju lati maa jọ sọọ nipa rẹ titi ti , a  o fi ri ojutuu si isoro ọhun sugbọn ẹ  maa bẹrẹ iyansẹlodi

“O seni laanu pe, orilẹ ede Naijiria nikan ni awọn dokita ti maa n da isẹ́ silẹ lasiko ti orilẹ ede naa ba n koju isoro nipa eto ilera. idi niyi ti a se n rọ̀ wọ́n , a o  dun ikooko mọ wọn. sugbọn a n bẹ wọn ni. ”

Minista tun tẹsiwaju  pe  eto ko sisẹ, ko sowo, ki i se ipinnu ijọba orilẹ ede Naijiria bi ki i se  ofin eto ilana  isẹ́   ajọ agbaye, pe ti o ko ba sisẹ , o lẹtọọ si owo gbigba , nitori owo ti wọn n san fun ọ , wá lati awọn to n san owo orí, nitori naa, o ko lee wa nile fun osu mẹfa , ki o ma reti owó isẹ́ ti o ko se.

Minisita tun sọ pe , gbogbo awọn ohun to n fa aawọ laarin ijọba apapọ ati awọn dokita lo jẹ pe  isoro ti awọn dokita abẹle ni pẹlu  ijọba ipinlẹ wọn ni , a si ti rọ wọn pe , ki wọn ba awọn ijọba ipinlẹ wọn sọrọ ni itubi-inubi nipa rẹ̀.

“Ninu awọn ohun mejila ti wọn n beere fun , meje ninu rẹ lo jẹ pe ikawọ awọn ijọba ipinlẹ lo wa , ki i se ikawọ ijọba apapọ, a si ti sọ fun awọn dokita naa pe ijọba apapọ ko lagbara lati pasẹ fun awọn ijọba ipinlẹ nipa iye owó osù ti wọn gbọdọ maa san fun awọn osisẹ wọn.

“ Awọn ohun to kan ti ijọba apapọ, pupọ ninu rẹ ko ni i se pẹlu ajọ eto ilera sugbọn a  seto iranwọ fun wọn .Idi niyi ti a fi  n sọ fun wọn pe , ko dara ,bi wọn se lọ fun iyansẹlodi yii, paapaa julọ nigba ti orilẹ ede n koju eto ipenija nipa ajakalẹ arun , ki i se asiko yii gan an lo yẹ ki awọn osisẹ eto ilera lọ fun iyansẹlodi, nigba ti awọn ọmọ orilẹ ede miran n fi ara wọn silẹ lati seranwọ fun orilẹ ede wọn.

O tẹsiwaju pe ijọba orilẹ ede Naijiria yoo tẹpẹlẹmọ  lati maa pàrọwọ̀ fun awọn dokita ati osisẹ eto ilera lati pada sẹnu isẹ́ wọn.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.