Take a fresh look at your lifestyle.

COVID-19: Ẹ jẹ́ kí á jọ gbógun ti ìpín kẹta àrùn COVID-19- Osagie Ehanire

112

igbimọ ijọba  orilẹ ede Naijria  ti ni ifọwọsowọpọ gbogbo awọn ọmọ orilẹ ede Naijiria nikan lo lee gbogun ti ipin kẹta  ajakalẹ arun Corona lorilẹ ede yii.

Minisita fun eto ilera lorilẹ ede Naijria, Osagie Ehanire,lo sọrọ yii lọjọBọ pẹlu awọn akọroyin.

O tẹsiwaju pe ;  ”Ti gbogbo awọn eniyan ba  se ojuse wọn , ti gbogbo wa ba fọwọsowọpọ , ki i se ijọba nìkan , eleyii ni se pẹlu gbogbo eniyan  ati gbogbo ile isẹ ijọba ati awọn akọroyin , eleyii lo lee ran wa lọwọ lati borí gbigbogun ti ìpín kẹta arun COVID-19.

“ Aseyọri ti a ti se nipa gbigbogun ti arun Corona lorilẹ ede Naijiria, nipa titẹle awọn ilana ti a ti la silẹ   ati gbigba abẹrẹ ajẹsara arun Corona lati igba ti arun COVID 19 ti bẹrẹ, ran wa lọwọ pupọ.Nitorina naa, gbogbo wa patapata, yala ijọba orilẹ ede , awọn akọroyin,ile-isẹ ti kii se ti ijọba, ile-isẹ aladaani, awọn ẹgbẹ́, awọn ọba, awọn adari ilu,,ni wọn ni ipa pataki lati ko, nipa gbigbogun ti arun Corona.” 

Ni bayii, iye awọn to ti ni arun COVID-19 ti jẹ ẹgbẹrun mọkandin-ni-ọgọ́sán.

“ Awọn ipinlẹ ti arun Corona ti gbilẹ̀ ni Lagos, Akwa Ibom, Rivers, Oyo, Ogun, Ekiti, ati ilu Abuja  Federal Capital Territory,”

Leave A Reply

Your email address will not be published.