Ìgbìmọ̀ aláṣẹ Nàìjíríà gbóríyìn fún Mínísítà fún Iṣẹ́ -ọ̀gbìn tí ó dolóògbé
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ aláṣẹ ní ọjọ́ọ́rú, gbóríyìn fún mínísítà fún iṣé-ọ̀gbìn ní orílẹ̀-èdè nígbàkan rí,tí ó dolóògbé ní ọjọ́ Àìkú.
Akowe fun Ijọba apapọ, Ọgbẹni Boss Mustapha kede iku Malami Buwai,tii ṣe ẹni ọdun mẹrindin-lọgọrin, o jẹ minisita fun iṣẹ -ogbin lati ọdun 1994 si 1996, labẹ ijọba aarẹ Sani Abacha ti ohun naa ti di oloogbe.
Igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo,ni o ṣagbatẹru Ipade igbimọ naa lori ayelujara, ṣe idakẹjẹ iṣẹju kan lati bu ọla fun Buwai ti o doloogbe, o si gbadura pe ki ọlọrun gbabọ rẹ.
Ọjọgbon Osinbajo n ṣe adari ipade naa, eyiti o bẹrẹ ni nnkan bi aago mẹwa aarọ ni akoko Naijiria, lati Yara Apejọ arabinrin Akọkọ, Villa, Abuja.
Awọn minisita ti o wa ni Villa fun ipade naa ni, Alhaji Lai Mohammed, iroyin ati Aṣa; Zainab Ahmed Isuna, Inawo ati Eto Orilẹ -ede; Abubakar Malami, Agbejoro Agba ati Idajo; Babatunde Fashola, Ise ati Ibugbe; ati Saleh Mamman, ina.
Ọga agba awọn Oṣiṣẹ fun Aarẹ, Ọjọgbọn Ibrahim Gambari; Igbakeji ọga agba fun awọn Oṣiṣẹ, Adeola Ipaye; Oludamoran Aabo Orilẹ -ede, Babagana Monguno; ati Akọwe agba, Ile olu-ilu , Tijani Umar, wa ni ipade naa.
Awọn alaye nigbamii.
Leave a Reply