Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Buhari pàṣẹ fún àwọn ilé-isẹ́ ológun àti agbófinró láti fòpin sí ìpanìyàn ní ìpínlẹ̀ Plateau

Ademọla Adepọju

59

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti fún àwọn ilé-isẹ́  ọmọ-ogun iorilẹ ede Naijiria ti o wa ni ìpínlẹ̀ Plateau ní ọjọ́ mẹwaa láti lé àwọn oníjàgídíjàgan tí wọ́n da àwọn ènìyàn tó wà ní àwọn agbègbè kọ̀ọ̀kan to wa  ní ìpínlẹ̀ Plateau láàmú.

Ààrẹ Buhari pàsẹ náà láti fi dẹ́kun àwọn ìwà ipaniyan , ajinigbe  àti bíba àwọn ohun ìní àwọn ènìyàn jẹ́ tó sì n yọrí sí yíyí ipò àwọn ènìyàn padà sí aburú, paápaa ní àwọn agbègbè Riyom àti Bassa ní Ìpínlẹ̀ Plateau.

Aarẹ Muhammadu Buhari si ti pasẹ fun ọgagun Ibrahim Ali láti pèse eto ààbò fún àwọn ará ìlú to wa ni Ipinlẹ Mẹfẹfẹa to n kopa ninu rogbodiniyan yii ni kiakia.

Oludari  ile-isẹ ologun, ọgagun Ibrahim Ali  ti ṣe abẹwo si diẹ ninu awọn ti wọn farapa ninu rogbodiniyan naa, lara wọn ni Miango, Biyei ati awọn miiran, o si fun wọn ni awọn nnkan bii apo iresi, awọn asọ ibora,paali indomie ati apo iyọ.

 

 

 

Hamzat Damola

Leave A Reply

Your email address will not be published.